Wọn ma fọlọpaa mu ọmọ mi o

Emi o le fi taratara da si ọrọ awọn Sẹki yẹn, ọrọ lọkọ-laya ni, nigba tẹni to si ni oun fẹẹ waa fẹjọ ọmọ mi sun ko ti wi kinni kan, mo mọ pe ko ti i ka a lara niyẹn, bo ba ka a lara, yoo sọrọ soke. N oo ṣa ni i sọ fun un pe iyawo ẹ waa ba mi pe o ni oun fẹẹ bimọ si i. Bo ba waa sọ fun mi, n oo mọ ẹjọ ti n oo da, ṣugbọn ti ko ba ti fẹnu ara ẹ sọ fun mi, Sẹki ni n oo ba sọrọ to ba ya.  Bi Akinfẹnwa ba waa ba mi, n oo ni ko fọgbọn tan iyawo ẹ ni, ko ṣe nnkan gidi mi-in fun un, ko tu u loju, bo ba ṣe daadaa, Sẹki le bimọ kan si i.  Owo kuku wa lọwọ wọn ti wọn yoo fi tọ wọn.

Beeyan o ba lowo lọwọ ni yoo ni ọmọ meji loun fẹẹ bi, bi owo ba wa, ko si ohun to buru ninu ọmọ mẹrin, nitori a ko mọ ọmọ ti yoo duro sin ni, ẹni ti ọmọ ba sin nikan naa lo bimọ. Iṣẹ ti emi o ṣe nibẹ ni pe n ko ni i jẹ ko lo oogun feto-sọmọ-bibi kan lasiko yii, ko ma ko piisi jẹ, ko si ma lọọ ki waya bọ ara ẹ loju ara, n oo ṣalaye fun un pe awọn iroyin ti mo maa n gbọ nipa kinni naa ko daa. Emi ṣaa ree, emi iya ẹ, mi o lo oogun kan ri. Oṣu ati taimu lemi n ka, ko si ja mi kulẹ ri, nitori ẹ ni n o ṣe lo piisi, n ko si ni i jẹ ki Sẹki naa lo o. Ṣugbọn ọkọ ẹ gbọdọ ṣe e daadaa.

Ọrọ Sẹki o le to gbogbo iyẹn, bi ọkọ ẹ ba ti ṣe e daadaa, to gbe nnkan tuntun kan le e lọwọ, yoo maa pariwo Dele kiri ni: ‘Dele ni o, Dele ni o!’ Ṣebi bo ṣe maa n ṣe tẹlẹ niyẹn. Ọrọ wọn yẹn o le loju emi rara. Eyi to tiẹ le, eyi to jọ pe o fẹẹ le, Ọlọrun ti ba mi yanju ẹ. Ọrọ ọmọ ti mo n sọ pe o loyun fun Akin yẹn ni.

Ọrọ naa ma fẹẹ le kọja ọrọ oloyun de, ti wọn si fẹẹ sọ ọrọ di nnkan mi-in mọ mi lọwọ. Ọlọrun lo ni ki oluwa ẹ naa jẹ eeyan, ki iṣẹ rere ati orukọ rere oluwa ẹ naa si ṣaaju. Ẹ wo o, onisọnu lawọn ọmọ ti a n bi yii jare. Isọnu wọn pọ paapaa!

Akin fun ọmọ loyun, ọmọ pasitọ! Ohun to di wahala niyẹn o. Eewọ ni nile awọn ọmọ yii lati lọọ fẹ Musulumi, wọn ni baba wọn buru debii pe o ti kọ akọbi ẹ lọmọ nitori iyẹn, pe wọn ko ti i yanju iyẹn lati ọjọ ti tọhun ti taku pe ọmọkunrin kan ti baba ati iya ẹ jẹ Musulumi loun fẹẹ fẹ. Wọn wa lẹnu iyẹn ki ọrọ awọn Akin too wọ ọ. Ohun ti Akin fi waa ba ọrọ naa jẹ ni pe ko sọ fẹnikan, koda ko sọ fun aunti ẹ ti wọn jọ n rira ni gbogbo igba, ka tiẹ ni ki i ṣe gbogbo igba lemi ati ẹ n rira. Titi ti ọrọ fi di gbẹgẹdẹ mọ ọn lọwọ, ko wi fẹnikan o. Wọn ti ti i mọle ka too gbọ o.

Ọmọ naa fẹran Akin. Tinukẹ ni Sẹki ni oun mọ ọn si, koda, Safu naa mọ ọn, nitori Akin ti mu un wa si ṣọọbu ri lọjọ kan ti emi o si nibẹ, Safu ni iwa ọmọ naa daa debii pe nigba to n lọ, ẹgbẹrun marun-un loun fun un lapo ara oun. Bẹẹ, emi o gbọ nnkan kan. Bawo ni ki n tiẹ ṣe gbọ, ṣe Akin ti ki i ba mi sọrọ. Bo o ba si ti beere ọrọ pe lọjọ wo ni yoo mu iyawo wale bayii, bii ẹni pe o kan an leewo ni. Yoo sa lọ kuro niwaju ẹ loju ẹsẹ ni. Ohun ti emi o ṣe mọ pe o ni Tinukẹ kan nibi kan niyẹn. Ṣugbọn Elizabeth ni wọn mọ ọn si ninu ile wọn.

Bi Akin si ṣe wa yẹn, kinni kan wa ti ki i fi ṣere, iyẹn ni pe ki i fẹ ki awọn eeyan ma mọ pe Musulumi loun. Ki i kirun taara o, ṣugbọn bii ko maa sọrọ ko sare sọ pe Walai, tabi ko ni Alau Akbaru, tabi ko ni Subuhanala, gbogbo iyẹn lawọn ọrẹ rẹ fi mọ ọn ni Musulumi o. Awọn mi-in tiẹ maa n fẹẹ pe e lorukọ ẹ, awọn ti wọn mọ ọn dele ni o, inu ẹ maa n dun ti wọn ba pe e ni Aloma, awọn ọrẹ ẹ ni o. Awọn ti wọn si n pe e ni Aloma ko mọ pe nitori orukọ ẹ ni. Idris. Wọn ni ọkunrin olowo ati alagbara kan ti wa nibi kan nigba kan to n jẹ Idiris Aloma.

Boya oun lo sọ ara ẹ bẹẹ ni o, boya awọn ọrẹ ni o, ṣugbọn nigba to ti wa ni ileewe girama ni wọn ti n pe e bẹẹ. Emi o waa mọ bo ṣe jẹ ọmọ pasitọ lo lọọ ba yii o. Wọn ni ọjọ ọrẹ wọn ti pẹ, awọn ti wọn mọ wọn naa ni nileewe girama ni wọn ti pade, nigba naa ni wọn si ti n ba ọrẹ wọn bọ. Ọrẹ ti wọn ti n ṣe lati bii ọdun mẹẹẹdogun sẹyin. Ṣugbọn wọn sọ pe latigba ti baba yẹn ti mọ pe ọrẹ wọn n le lo ti n kilọ fun ọmọ rẹ, iyẹn lẹẹkọọkan to ba wa sile wọn. Nigba to si ya, Akin o dele wọn mọ, nigba to jẹ ojoojumọ niyẹn n lọọ ba Akin nile ẹ.

Kẹ ẹ maa wo awọn ọmọ yii o, o ni oun ko gbe ile wa, ile merẹnti loun n lọọ gbe, to tun jade nibẹ, to ko wa sile mi nibi to fi ṣe ọọfiisi, aṣe ọrọ ọmọ Tinukẹ yẹn wa nibẹ. Emi o kuku mọ. Gbogbo bi ọrọ si ti n di wahala nile awọn ọmọ yii, ti pasitọ n kilọ fun un lojoojumọ pe ko ma fẹ Musulumi, ko gbọdọ mu Musulumi waa ba oun, gbogbo ẹ ni ọmọ yẹn n sọ fun Akin temi o. Kaka ko si sọ nile ka le mọ ohun ti a oo ṣe, niṣe ni wọn n fi ọrọ naa rẹrin-in laarin ara wọn, pe ko si wahala. Ṣe bi emi ba gbọ, n ko ti ni i le e nidii ẹ. Abi ọran ni wọn fi n fẹẹyan ni.

Loootọ o maa wu mi ki ọmọ mi fẹ Musulumi, ṣugbọn to ba jẹ Kristiẹni naa lo fẹ, ko si ohun to buru ninu ẹ lọdọ temi, ohun ti n ko kan fẹ naa ni ki ẹnikan maa wa fi ọrọ ẹsin tiẹ yọ emi naa lẹnu, onikaluku lo lẹsin tiẹ. Ohun to dun mi ju ninu ọrọ yẹn niyẹn. Sẹki ni Tinukẹ funra ẹ lo ni afi ki oun loyun, Akin kọ fun un. Nigba ti ko si fi i lọrun silẹ lo fi loyun yii. Wọn lo ni ohun to le yi baba oun lọkan pada niyẹn. N lọmọ ba loyun, lo di wahala, ni wọn ni baba ẹ ba yari, lo ni ti oun ba ri Akin, oun maa bẹ ẹ lori. Lo ni ki ọmọ ko jade nile oun o.

Nigba ti ọmọ o si ni ibi meji ti yoo ko lọ, ọdọ Akin naa lo ko wa. Wọn waa ni aburo ẹ kan to ti maa n ba a wa sọdọ Akin naa lo lọọ ṣofofo pe ibẹ lo ma wa. Ni pasitọ ba lọọ fi ọlọpaa mu ọmọ temi o, lo ni o ji ọmọ gbe. Ẹ gbọ, nibi ti aye le de bayii, keeyan ni ki ọlọpaa lọọ mu ẹnikan pe o ji ọmọ gbe! Eyi ti mo ri niyẹn o!

Leave a Reply