Faith Adebọla, Eko
Bo ba jẹ ootọ ni ọrọ kan ti aṣofin to n ṣoju awọn eeyan Aarin-Gbungbu Kaduna tẹlẹ, Sẹnetọ Shehu Sanni, kọ sori opo ayelujara tuita rẹ nirọlẹ ọjọ Abamẹta, Satide yii, a jẹ pe idunnu ti ṣubu lu ayọ fọpọ awọn ololufẹ ati alatilẹyin Adari ẹgbẹ oṣelu APC nni, Bọla Ahmed Tinubu, tori ọkunrin naa kọ ọ sibẹ pe Tinubu ti pada de si Naijiria o.
Ọrọ ti ọkunrin naa kọ soju opo rẹ ni:
“Ọkan lara awọn ọrẹ mi lọọ ra tikẹẹti lati ṣabẹwo si Jagaban (Tinubu) niluu London, lorileede United Kingdom to wa, ṣugbọn o ya a lẹnu nigba to de’bẹ ti wọn fidi ẹ mulẹ fun un pe Tinubu ti pada sile, wọn lo ṣẹṣẹ pada si Naijiria lati London ni. Mo ki Aṣiwaju ku oriire o.”
Bo tilẹ jẹ pe titi dasiko ti a fi n ko iroyin jọ, ko ti i ṣee ṣe lati fidi otitọ ọrọ yii mulẹ, tori Oluranlọwọ pataki rẹ, Ọgbẹni Tunde Rahman, ko gbe aago rẹ, ko si ti i fesi si atẹjiṣẹ ta a fi ṣọwọ si i.
Tẹ o ba gbagbe, o ti ju oṣu meji lọ ti gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ naa ti lọ si London fun itọju. A gbọ pe wọn ṣiṣẹ abẹ pataki kan fun baba ẹni ọdun mọkandinlaaadọrin naa.
Niṣe lero si n wọ bii omi lọ si ile ọkunrin naa, paapaa awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC, atawọn eeyan pataki pataki mi-in ti wọn n lọọ ki i, ti wọn si n ya fọto pẹlu rẹ. Aarẹ wa, Muhammadu Buhari, wa lara awọn to kọkọ yọju si Tinubu, bẹẹ lawọn gomina ilẹ Yoruba naa ṣe bakan naa lọkan-o-jọkan.