Wọn ma ti gbe ọpa aṣẹ Ọba Akiolu laafin

Faith Adebọla, Eko

Ẹkọ ko ṣoju mimu rara ni aafin Eleko ti Eko, Ọba Rilwan Akiolu pẹlu bi aọn ọdọ kan ṣe ya bo aafin rẹ ti wọn si dana sun un. Ki i ṣe pe wọn dana sun aafin yii nikan, niṣe ni wọn binu gbe ọpa aṣẹ kabiyesi kuro laafin, ti wọn gbe e sa lọ. Ninu fidio kan tawọn ọdọ naa ju sita ni wọn ti ṣafihan ibi ti wọn ti n gbe ọpa kabiyesi sa lọ.

Ko sẹni to ti i le sọ ibi ti Ọba Akiolu funra ẹ wa lasiko ta a n kọ iroyin yii.

Sugbọn kinni kan to daju ni pe awọn ọdọ ti dana sun aafin ọba Eko yii, wọn si ti gbe ọpa asẹ rẹ lọ.

2 thoughts on “Wọn ma ti gbe ọpa aṣẹ Ọba Akiolu laafin

  1. Ara ń ní àwa ọmọ orí lédè Nigeria, kí àwọn tí ẹnu wọn tọrọ láwùjọ má ṣe dakẹ kí wọn ó má wo ran bákan náà emi ó fara mọ ohun tí àwọn ọdọ ṣe yí,

Leave a Reply