Wọn maa too tu Sunday Igboho silẹ lahaamọ-Ọlajẹngbesi

Faith Adebọla
Pẹlu ọrọ ti Ọgbẹni Pẹlumi Ọlajẹngbesi, ilu-mọ-ọn-ka lọọya to n ṣoju fun gbajugbaja ajijangbara ilẹ Yoruba nni, Oloye Sunday Adeyẹmọ tawọn eeyan mọ si Sunday Igboho, sọ lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ karun-un, oṣu keji yii, ireti to daju wa pe Sunday Igboho yoo kuro lahaamọ ẹwọn orileede Olominira Benin ti wọn ti i mọ, yoo si dẹni ominira laipẹ.
Ọlajẹngbesi lo ṣofofo ọrọ naa sori atẹ ayelujara rẹ, lori ikanni Fesibuuku to n lo, o kọ ọ sibẹ pe:
“Oloye Sunday Igboho yoo jade laipẹ, iro ayọ ati idunnu yoo si sọ kaakiri ilẹ Yoruba pata. Ko si iyemeji nibẹ pe akikanju ọkunrin gidi ni.”
Ọlajẹngbesi fi kun un pe: “Ọrọ to fidi mulẹ daadaa ni mo n sọ o, o kan jẹ pe awọn aṣaaju ilẹ Yoruba wa yii gbọdọ lọọ wa ọwọ iwa abosi, imọtara-ẹni-nikan, bọlẹ, ki wọn si gba ki iwa rere leke.”
Bẹẹ lọkunrin naa kọ ọ sori opo ayelujara rẹ, bo tilẹ jẹ pe ko ṣalaye kan nipa awọn agbaagba Yoruba to n ba wi, ko si sọ pato ohun ti wọn ṣe to pe ni iwa abosi ati imọtara-ẹni-nikan.
Tẹ o ba gbagbe, ọjọ mẹta sẹyin, lọjọ Tọsidee to kọja yii,  ni ẹgbẹ Agbẹkọya Kari-aye (Agbẹkọya Worldwide) ṣewọde alaafia kan niluu Oṣogbo, ipinlẹ Ọṣun, nibi ti wọn ti n beere pe kijọba apapọ ni Naijiria yọnda fun orileede Bẹnẹ lati tu ọkunrin naa silẹ.
Aarẹ ẹgbẹ Agbẹkọya ọhun, Ọgbẹni Kamọrudeen Okiki, sọrọ l’Ọjọbọ ọhun pe: “Sunday Igboho ki i ṣe ọdaran. A o ni i ye tẹnu mọ koko yii. A mọ pe ijọba apapọ (Naijiria) lo mu un mọlẹ ni orileede Olominira Benin, ṣugbọn a n fi asiko yii sọ fun awọn alaṣẹ orileede Olominira Benin pe ki wọn lo ile-ẹjọ wọn ati ofin lati tu u silẹ lominira.
“Wọn gbọdọ da a silẹ lominira lọna to bofin mu ni, o si gbọdọ jẹ ni kiakia pẹlu, aijẹ bẹẹ, a maa lo agbara abalaye ati ọna ibilẹ lati mu un jade kuro lahaamọ o.”
Ṣe, lati oṣu keje, ọdun to kọja, lawọn agbofinro ti mu Sunday Igboho ati iyawo rẹ, Rọpo Adeyẹmọ, sahaamọ, niluu Kutọnu, lorileede Benin, lasiko ti wọn fẹẹ wọ baaluu lọ sorileede Germany.
Bo tilẹ jẹ pe wọn ti fi iyawo rẹ silẹ lẹyin ọjọ diẹ, o ti ju igba ọjọ lọ bayii ti Oloye Sunday Adeyẹmọ ti wa lahaamọ lorileede Benin, bẹẹ ni wọn ko ba a ṣẹjọ, wọn ko si fi i silẹ.

Leave a Reply