Wọn mu alaga kansu pẹlu ayederu iwe idibo, maggi, owo atawọn nnkan mi-in

Jọkẹ Amọri

Alaga ijọba ibilẹ Obi, nipinlẹ Nasarawa, Joshua Zheyekpuwudu, yoo rojọ, ẹnu rẹ yoo fẹrẹ bo, lakata awọn ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ ipinlẹ naa ti wọn mu un lori ohun ti ayederu iwe idibo, owo ti wọn ni o ṣee ṣe ko fẹẹ fi ra awọn oludibo, maggi isebẹ, Indomine, atawọn nnkan mi-in ti wọn ba lọwọ rẹ.

Ni agbegbe kan ti wọn n pe ni Tundun Kauri, niluu Lafia, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ naa ni awọn ọtẹlẹmuyẹ ti da ọkọ ti ọkunrin naa pẹlu awọn ọmọọṣẹ rẹ kan wa ninu rẹ duro laaarọ ọjọ idibo lati beere ibi ti wọn n lọ, niwọn igba ti ijọba ti kede pe ko gbọdọ si igboke gbodo ọkọ lasiko eto idibo naa.

Iyalẹnu lo jẹ fawọn agbofinro naa nigba ti wọn ri ayederu iwe idibo, owo, maggi isebẹ indomine atawọn nnkan mi-in ti ireti wa pe ọkunrin naa fẹẹ pin fun awọn oludibo ki wọn le baa dibo fun ẹgbẹ rẹ lọwọ re.

Nigba ti wọn beere ohun to fẹẹ fi awọn nnkan naa ṣe, ko ri idahun gidi kan mu wa. Ni wọn ba gbe e janto, o di ileeṣẹ wọn. Nibẹ lo wa titi ta a fi pari akojọpọ iroyin yii to n ran ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ lọwọ lori bi awọn nnkan naa ṣe de ọwọ rẹ atawọn to fẹẹ lọọ ko o fun.

 

Leave a Reply