Wọn mu Henry fẹsun idigunjale l’Ondo, lo ba lawọn ọrẹ oun lo ko b’oun

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ṣe lọmọkunrin ẹni ọdun mọkandinlogun kan, Henry Ọlamide, n ge ika abamọ jẹ lasiko to fara han niwaju adajọ nile-ẹjọ Majisreeti karun-un to wa l’Oke-Ẹda, niluu Akurẹ, nibi to ti n jẹjọ ẹsun mẹta ti wọn fi kan oun atawọn ẹgbẹ rẹ mẹrin tawọn ọlọpaa ṣi n wa.

Lara awọn ẹsun ti wọn fi kan afurasi ọhun ni fifipa gbowo lọna aitọ ati didi oṣiṣẹ ẹsọ Amọtẹkun kan ti wọn porukọ rẹ ni Michael Babade lọwọ lẹnu iṣẹ rẹ.

Awọn ẹsun wọnyi ni agbẹnusọ fun ijọba ipinlẹ Ondo, Amofin O. F. Akeredolu, ni o ta ko iwe ofin orilẹ-ede yii tọdun 2004, ati ofin idasilẹ ẹsọ Amọtẹkun ipinlẹ Ondo ti ọdun 2020.

Agbẹjọro ọhun ni ọjọ kẹwaa, osu kẹwaa, ọdun ta a wa yii, lọwọ tẹ afurasi ọhun nibi toun atawọn ẹgbẹ rẹ mẹrin mi-in ti gbe igi di ọna lọsan-an gangan laarin oju ọna marosẹ Ọrẹ siluu Ondo, ti wọn si n fipa gbowo lọwọ awọn awakọ to ba n kọja lagbegbe naa.

O ni awọn kan wa lara ẹsun mẹtẹẹta yii tile-ẹjọ Majisreeti ko lagbara lati gbọ labẹ ofin, idi niyi to fi rọ ile-ẹjọ lati gba ki afurasi ọhun ṣi wa lọgba ẹwọn titi ti wọn yoo fi ri imọran gba lati ọfiisi ajọ to n gba adajọ nimọran.

Nigba to n fesi si ibeere ti adajọ beere lọwọ rẹ, Henry ni kọkọrọ yara oun to sọnu lọjọ kan lo sọ oun dero Sabo, niluu Ondo, lati lọọ duro laarin awọn Hausa tí wọn ki i sun mọju.

Latibẹ lo ni oun ti topasẹ awọn ọrẹ oun kan lọ sibi ti wọn ti n dana, ti wọn si n fipa gbowo lọwọ awọn awakọ to n kọja.

O ni loootọ ni wọn gba oun nimọran lati darapọ mọ wọn ti oun si gba lẹyin ti wọn ṣeleri ati pin oun naa lara owo ti wọn ba pa.

Afurasi ọhun ni wọn fun oun ni igi kan lati mu dani nigba tawọn yooku naa mu nnkan ija tiwọn lọwọ, eyi ti wọn fi n halẹ mọ ẹnikẹni ti ko ba fẹẹ fun wọn lowo.

O ni eyi ni awọn n ṣe lọwọ ti ẹsọ Amọtẹkun fi de, ti wọn si gbiyanju ati fi panpẹ ofin gbe awọn, ṣugbọn ti awọn rọna sa mọ wọn lọwọ.

Henry ni awọn ẹsọ ọhun pada ri oun mu lẹyin ọjọ diẹ, ti wọn si mu oun lọ si ọfiisi wọn, nibi ti oun wa titi ti wọn fi mu oun wa sile-ẹjọ.

Nigba to n gbe ipinnu rẹ kalẹ, Onidaajọ D. S. Ṣekoni gba ẹbẹ agbẹnusọ fun ijọba wọle, bẹẹ lo sun igbẹjọ mi-in si ọjọ kọkandinlogun, osu kin-in-ni, ọdun 2022.

 

Leave a Reply