Wọn n wa wọn o: awọn ọmọ Kutọnu meji to pa ọga wọn n’Ikorodu

Aderounmu Kazeem

Ọkunrin meji kan nileeṣẹ ọlọpaa n wa bayii lori ẹsun wi pe wọn ṣeku pa ọga wọn, Alhaji Rabin Owolabi Oyenuga, lẹyin ti wọn ko o lowo, ti wọn si tun ko goolu rẹ lọ.

Biodun ati Joseph, ni wọn pe orukọ awọn mejeeji yii, bẹẹ ọmọ ilu Cotonou, lorilẹ-ede Benin Republic ni wọn pe wọn pelu.

Owurọ kutu Ọjọbọ, Tọsidee, ana yii ni iṣelẹ buruku yii waye niluu Ikorodu, nigba ti awọn ọmọkunrin meji yii kọlu ọga wọn, ti wọn si yin in lọrun titi to fi ku mọ wọn lọwọ.

Ọkan lara awọn to maa n bani-kọle ni Alhaji Rabin Owolabi Oyenuga niluu Ikorodu, l’Ekoo. Ọmọ ẹ, Adetola, to ba awọn oniroyin sọrọ sọ pe idaji miliọnu lowo ti wọn ko lọ, ati goolu baba naa pẹlu awọn ohun mi-in to jẹ olowo nla.

Adetola fi kun un pe; “Akaba ni wọn gun fi wọnu orule to ja si yara baba mi, bi wọn ti ṣe wọ yara wọn ni wọn ga wọn lọrun, ti wọn si yin wọn lọrun pa. Lẹyin ti wọn ṣiṣẹ ibi wọn tan ni wọn ko owo, ti wọn ji goolu gbe atawọn ohun miiran, ki wọn too bọ iboju wọn sẹnu geeti, ti wọn si gba ibẹ salọ.”

 

 

Leave a Reply