Faith Adebọla
Bi wọn ba n sọ pe ẹnu ki i si lara afọkeemu, tabi pe ọrọ gbogbo ki i se lori alabahun, ẹnikan ti ọrọ naa ba mu gẹlẹ ni Habeeb Okikiọla, ọkunrin olorin taka-sufee tawọn eeyan mọ si Portable tabi Zaa zuu zeh.
O jọ pe inu igbago ni mariwo n ṣe ẹṣọ, idọbalẹ si ti dara fejo irawọ oṣere yii, pẹlu bo ṣe maa n sọ ọrọ gbau gbau to le ko o si wahala, o ṣe tan, gẹgẹ bii aṣa to maa n da, wahala, wahala wahala ki i wọn ninu ọrọ ati iṣe rẹ.
Tuntun ti Zah zuu tun ṣe lopin ọsẹ yii ni fidio ara ẹ kan to gbe sori ikanni instagiraamu rẹ, nibi to ti n fara ya pe awọn eeyan ṣe gbaju-ẹ foun lode ariya kan toun lọ niluu Ṣagamu, nipinlẹ Ogun, o ni wọn na oun lowo, amọ nigba toun dele, toun yẹ owo toun pa wo, feeki lawọn owo naa, ayederu lo pọ ninu ẹ.
Portable ni: ‘Ha, igboro ti daru ooo, tete fi owo to ba ṣeku lọwọ ẹ ra kala, tori agbo ọdaju lo ku bayii. Emi naa maa lọọ da banki apapọ temi silẹ, Central Bank of Zeh Nation’ mo dẹ maa maa tẹ owo funra mi, ma a ra ẹrọ ti wọn fi n tẹ owo.
‘‘Bizza Bizza ile Afrika lo n sọrọ o, I-ka, Huwa Ika, Ṣe ika ko tirafuu, ilu ti le o, wahala wahala wahala’’ ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Bayii ni Portable to gbogbo aṣa ati ede akanlo rẹ jọ, bo ṣe n laagun bọyọ pẹlu awọtẹlẹ buluu kan to wọ sidii, ti ko si si aṣọ kan lọrun rẹ ju fila to de sori lọ, o ko awọn owo naa sori tabili kan, o jokoo ti i, bo ṣe n ranju wọn-ọn, bẹẹ lo n fibinu sọ pe tawọn eeyan ba ti fẹẹ pe oun lode ariya lati asiko yii lọ, wọn gbọdọ sanwo elere, ki wọn sanwo sikiọriti, wọn si tun ni lati san awọn owo mi-in tori aibaamọ.
Portable ni bawo ni oun toun jẹ ọga olorin ṣe maa lọ sode ariya ti wọn maa maa ba mọto oun jẹ, tabi fọ gilaasi ọkọ oun. Oun o le gba iru ẹ.
Amọ awọn ololufẹ Portable ti la a lọyẹ lori ikanni instagiraamu ẹ lori ọrọ ọhun.
Ẹnikan to pe ara ẹ ni Adokiye sọ pe: Fauṣa (vouchers) ni wọn na fun ẹ, ki i ṣe owo feeki. Ofin tuntun ti banki apapọ ṣe ni. Sọ fun manija ẹ ko lọọ ba awọn ti wọn ṣeto ariya yẹn, wọn maa ṣiro iye ti voucher naa ba jẹ, wọn si maa ṣe tiransifaa owo to dọgba pẹlu rẹ sinu akaunti rẹ loju-ẹsẹ. Ki i ṣe feeki o.
Ẹlomi-in tun kọ ọrọ pe: Portable, ẹẹmelo ni mo pe ẹ, iwọ gbiyanju lati ra ẹrọ itẹwo na, igba yẹn lo ṣẹṣẹ maa ri wahala, wahala, wahala too maa n sọ. Ibi to o ti maa ba ara ẹ, ẹnu mi kọ lo ti maa gbọ ọ o.
Amọ ọtọ loju ti Joker-Ledger fi wo iṣẹlẹ yii, o ni: O yẹ kawọn mẹta ti mo fẹẹ darukọ wọn yii, Ọlamide, Kogbagidi ati Pocolee tọrọ aforiji lọwọ awa ọmọ Naijiria fun bi wọn ṣe gbe idaamu adugbo yii waa ka wa mọ, ti wọn sọ ọ di olorin, tori gbogbo nnkan ta a mọ nipa ẹ ko kọja wahala ati ijangbọn, ki i ṣe ohun ta a fẹ leyi.