Wọn ni ara Sunday Igboho ko ya ni Bẹnnẹ o

 Adefunkẹ Adebiyi

Ẹbẹ kan lawọn eeyan Oloye Sunday Adeyẹmọ ( Igboho Ooṣa) n bẹ Aarẹ ilẹ Bẹnnẹ, Patrice Talon, bayii. Ẹbẹ naa si ni pe ki ọkunrin naa yọnda Igboho lati lọọ gbatọju, nitori ara rẹ ko ya bayii o, o si nilo itọju kiakia ki nnkan kan ma baa ṣẹlẹ si i laburu.

Agbẹnusọ Igboho, Ọlayọmi Koiki, lo fi atẹjade to fi n kegbajare naa sita, nibi to ti ṣalaye pe lẹyin toun ti ba awọn agbẹjọro Igboho sọrọ, oun fidi ẹ mulẹ funjọba Bẹnnẹ to tọju Sunday Igboho sahaamọ lati ogunjọ, oṣu keje, ọdun 2021, pe ara ọga oun ko ya bayii o.

O ni ko sohun meji to le ṣe e lanfaani bayii ju ki ijọba orilẹ-ede Bẹnnẹ fun un laye, ko lọọ tọju ara rẹ kiakia.

Wọn tilẹ ṣapejuwe Aarẹ Patrice Talon bii ẹni to ni eti igbọ ati aya igbaṣe, ẹni to maa n ro ti ara yooku mọ tirẹ, ti ireti si wa pe yoo fun Sunday Igboho laaye lati lọọ tọju ara rẹ.

Bẹ ẹ o ba gbagbe, orilẹ-ede Germany ni ajijagbara ọmọ Yoruba naa n lọ logunjọ, oṣu keje, ọdun yii ti wọn fi mu oun ati iyawo rẹ ni Bẹnnẹ, ki wọn too pada fi iyawo rẹ silẹ, ti wọn si ti Igboho mọlẹ.

Latigba naa lo ti wa nilẹ awọn Ajaṣẹ yii, ti ẹjọ rẹ ko si ti i fori sọ ibikibi.

Leave a Reply