Wọn ni awọn awakusa pa Wumi olounjẹ sinu oko n’Ibodi, lawọn ọdọ ba fẹhonu han

Florence Babaṣọla

Lọwọlọwọ bayii, niṣe ni ilu Ibodi, nijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Atakumọsa, n gbona janjan, tawọn ọlọpaa n pẹtu sawọn ninu ọdọ lati bu omi suuru mu.

Ọkunrin kan la gbọ pe o lọọ fi to awọn ọlọpaa leti pe iyawo oun, Wumi Babatọpẹ, lọọ ta ounjẹ labule Afọn lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ti wọn ko si gburoo rẹ mọ.

Kia lawọn ọlọpaa atawọn ọdọ agbegbe naa bẹrẹ si i wa Wumi kaakiri, ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ fun wọn nigba ti wọn ba oku ọmọbinrin naa nihooho ninu koto kan labule ọhun.

Igbagbọ awọn ọdọ ọhun ni pe awọn awakusa to pọ ju labule na ni wọn pa a nipakupa, wọn si bẹrẹ si i kọ lu awọn awakusa ti wọn n ṣiṣẹ nibẹ.

A gbọ pe wọn ti n dana sunle awọn awakusa naa, ṣugbọn Alukoro ọlọpaa l’Ọṣun, SP Ọpalọla, sọ pe awọn ti n bẹ awọn ọdọ naa, ati pe alaafia yoo pada sagbegbe ọhun laipẹ.

Leave a Reply