Wọn ni iṣẹ adigunjale ati ẹgbẹ okunkun lawọn ọmọọdun mọkandilogun yii n ṣe l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko

Boya lawọn gende mẹta tọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ba lọjọ Abamẹta, Satide yii, maa ri ọṣẹ fi wẹ mọ ninu ẹsun ti wọn fi kan wọn o, tori ẹsun mẹta ọtọọtọ ni wọn mu wọn fun, wọn ladigunjale ni wọn, wọn tun n ṣẹgbẹ okunkun, bẹẹ ni wọn n daluru.

Orukọ awọn afurasi ọdaran ọhun ni Victor Alfred, Chibuike Ike Donatus ati Isiaka Ọlamide, ko sẹni tọjọ-ori pe ogun ọdun ninu wọn, ọmọ ọdun mọkandinlogun pere lawọn mẹtẹẹta.

Nnkan bii aago mẹta kọja iṣẹju mẹẹẹdọgbọn afẹmọju ọjọ Satide naa ni wọn lọwọ ba wọn nibi ti wọn ti n dọgbọnkọgbọ lati fo fẹnsi ileetura Marble Guest House to wa ni Ojule kẹtalelọgbọn, Opopona Ajibikẹ, Ogudu, lagbegbe Ọjọta, nipinlẹ Eko.

Olobo kan ni wọn lo ta ileeṣẹ ọlọpaa nipa irin kọsẹ-kọsẹ tawọn ọkunrin naa n rin, wọn lawọn aladuugbo kan ti wọn taji lati jẹ saari lasiko aawẹ to n lọ lọwọ yii ni wọn kegbajare sawọn ọlọpaa, ni wọn ba waa fi pampẹ ofin gbe wọn, wọn si fi ṣẹkẹṣẹkẹ yẹ ọwọ wọn si.

Nigba ti wọn tu ara wọn wo, wọn ba ibọn Beretta kan, igbo ati oogun abẹnu gọngọ lọwọ wọn.

Wọn lawọn afurasi naa jẹwọ fawọn ọlọpaa pe loootọ lawọn jẹ adigunjale, ṣugbọn ki i ṣe awọn nikan, awọn ni ikọ tawọn jọ maa n ṣiṣẹ, ati pe ki i ṣe igba akọkọ tawọn n fọle onile niyi.

Bi Hakeem Odumosu, Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, ṣe gbọ nipa iṣẹlẹ yii lo ti paṣẹ ki wọn taari awọn tọwọ ba yii si Panti, Yaba, ki wọn le ran awọn agbofinro lọwọ lati le ri awọn yooku ti wọn jọ n ṣiṣẹ gbewiri mu.

Wọn ni tiwadii ba ti pari, ko sohun to maa da wọn duro lati foju wọn bale-ẹjọ ki wọn le gba idajọ to tọ si wọn.

Leave a Reply