Wọn ni ijọba ana ta ilẹ ileeṣẹ ipese omi ẹrọ, ni wọn ba fi kọ ileepo ni Kwara

Stephen Ajagbe, Ilorin

Aṣiri teeyan kan ko mọ ri nipa bi ijọba ana, labẹ idari Abdulfatah Ahmed, ṣe ta ilẹ ileeṣẹ ipese omi ẹrọ, iyẹn Ọlalọmi Water Reservoir, eyi to wa lọna Ira, niluu Ọffa, ti wọn si fi ilẹ naa kọ ileepo ti n tu sita bayii.

Oṣiṣẹ-fẹyinti kan, Samuel Ajide, (Area Land Officer), ṣalaye fun igbimọ to n ṣewadii dukia ijọba lọjọ Aje, Mọnde, pe wọn fi ilẹ naa silẹ tẹlẹ lati fi kọ nnkan lọjọ iwaju ni, ṣugbọn lojiji nijọba ni ki wọn ta a fun ẹni to ba nifẹẹ si i.

O ni obinrin kan, Alhaja Bintu Lawal, lo fifẹẹ han si ilẹ naa loṣu kẹwaa, ọdun 2015, lati fi kọ ileepo.

Ajide ni obinrin naa san miliọnu meje sinu akanti oun, ọpọlọpọ owo yẹn loun si san sapo awọn ileeṣẹ ijọba, ṣugbọn dipo ileepo ti onitọhun fẹẹ kọ, ile teeyan n gbe ni wọn pada ni o le kọ sori ilẹ naa.

“Ṣaaju gan-an, ileeṣẹ ijọba to n mojuto ọrọ omi (Ministry of Water Resources) ta ku pe ilẹ naa ki i ṣe eyi ti aladaani le ra, ati pe fun ọjọ iwaju ni wọn ṣe fi silẹ. Ṣugbọn Alhaja Lawal lọọ ba aṣofin tẹlẹ, Hassan Oyeleke, iyẹn lo lọọ ba a ri Gomina Abdulfatah Ahmed, to fi di pe wọn pada yọnda ilẹ naa fun un lati kọ ile.”

Ṣugbọn Alhaja Lawal fẹsun kan Ọgbẹni Samuel Ajide pe o lẹdii aapo pọ pẹlu awọn kan lati lu oun ni jibiti lori ọrọ ilẹ naa.

Ninu awijare rẹ, o ni: “Ọdun 2015 ni Ajide fọrọ ilẹ naa to mi leti. Ohun to sọ fun mi ni pe ijọba loun ṣi ba n ṣiṣẹ, aṣe o ti fẹyinti ti mi o mọ. Koda, gbogbo igba to fi wa ta a fi n dunaa-dura, ọkọ ijọba lo maa n gbe wa. Ori miliọnu mẹwaa la ti bẹrẹ ko too di pe a fori ẹ ti si miliọnu meje naira.

“Ajide ko ri iwe ilẹ kankan ko kalẹ. Mo ni lati lọọ ba Ọnarebu Hassan Oyeleke ko too di pe mo pada ri (C of O) ilẹ naa gba lọdun 2018. Koda, owo ti mo pada na gan-an ju miliọnu meje naira lọ”.

Alhaji Yunus Kọla Ọlatinwọ to gbẹnusọ fawọn araadugbo Ọlalọmi, nibi ti ilẹ naa wa, sọ pe iyalẹnu lo jẹ fawọn bi wọn ṣe n kọ ile sibẹ, nitori pe yoo ṣe akoba fun awọn ọpa omi ti wọn ri mọlẹ. O ni ilu Ọffa gan-an ko fọwọ si tita ilẹ naa.

Awọn Ọga agba ileeṣẹ ijọba to n mojuto ọrọ ilẹ tẹlẹ, Alhaji Abdulwahab Babatunde Yusuf ati Alhaji Ibrahim Salman, ti wọn fiwe pe kọ lati yọju si igbimọ naa.

Agbẹjọro wọn, Yunus Lambo Akanbi, ni wọn ko tete ri lẹta naa gba ni ko jẹ ki wọn le yọju.

Alaga igbimọ ọhun, Adajọ Ọlabanji Orilonishe, paṣẹ fun agbẹjọro naa lati ri i pe awọn onibaara rẹ yọju lọjọ Ẹti, Furaide, ọsẹ yii, lati waa sọ tẹnu wọn.

 

Leave a Reply