Wọn ni ileeṣẹ apinna-ka fẹẹ fi kun owo ina ijọba, ṣugbọn awọn eeyan naa ni irọ ni

Jọkẹ Amọri

Bi wọn ko ba yi ipinnu wọn pada, a jẹ pe afikun yoo ba owo ti awọn ọmọ Naijiria to n lo ina ẹlẹntiriiki yoo maa san lati ọjọ kin-in-ni, oṣu kẹsan-an, ọdun yii.

Ileeṣẹ to n ṣakooso ina pinpin nilẹ wa, Nigerian Eletricity Regulatory Commision (NERC),  la gbọ pe wọn ti paṣẹ fun awọn ileeṣẹ to n pin ina ka, iyẹn Electricity Distribution Comapnies (DisCos), lati fowo kun owo ti wọn n gba lati ọjọ kin-in-ni, oṣu kẹsan-an, ọdun yii.

Ninu iwe kan ti wọn kọ si ileeṣẹ apinaka yii ni wọn ti fun awọn ileeṣẹ to n pin ina yii ni agbara lati maa gba owo wọn lori bi wọn ba ṣe pese ina si, eyi ti awọn oloyinbo n pe ni service based tariff. Eyi to tumọ si pe bi wọn ba ṣe muna wa to naa ni owo ti awọn araalu yoo san yoo ṣe pọ to.

Bo tilẹ jẹ pe loootọ ni wọn gbe iwe yii jade, sibẹ, ọga agba ileeṣẹ Eko Electricity Distribution PLC, Ẹnjinnia Adeoye Fabiyi sọ pe irọ to jinna si ootọ ni ọrọ naa. Ninu iwe kan ti ọga agba ileeṣẹ naa fọwọ si lo ti sọ pe wọn ti fi ahesọ kan to n lọ pe awọn fẹẹ fi owo kun owo ina to awọn leti. O ni ko si ohun to jọ bẹẹ rara, ati pe iroyin ti ko ba ti wa latori ẹrọ agbọrọkaye awọn, kawọn eeyan ma gba a gbọ. O ni bo tilẹ jẹ pe awọn n dọgbọn si gbogbo nnkan pẹlu ọna ti ayipada n gba ba gbogbo nnkan, ti nnkan si n gbowo lori, eyi to n ṣakoba fun awọn araalu to n lo ina ijọba paapaa, sibẹ o ni awọn yoo fi to awọn araalu leti ti awọn ba ṣetan lati fowo kun owo ina.

Leave a Reply