Wọn ni Isaac mu nnkan ọmọkunrin Ṣeyi l’Ọta, ni ‘kinni’ ẹ ko ba ṣiṣẹ mọ

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Titi di asiko ti a n kọ iroyin yii, nnkan ọmọkunrin Ṣeyi Azeez, ẹni ọdun marundinlogoji (35) to n gbe ni Ọta, nipinlẹ Ogun, ko ti i ṣiṣẹ. Niṣe lo dẹnukọlẹ ti ọkunrin naa ko si le ṣe bii ọkunrin.

Ẹnikan ti wọn jọ n gbele ti wọn pe orukọ ẹ ni Isaac Adetunji ni awọn ọlọpaa sọ pe o ko ba Ṣeyi, nitori alaye ti wọn ni Ṣeyi ṣe fawọn lọjọ keji, oṣu kẹjọ, to waa fẹjọ sun ni teṣan Onipaanu ni pe jẹẹjẹ oun loun fẹẹ lọọ ra ọṣẹ iwe lọjọ naa, boun ṣe pade Isaac lọna to ni oun riran soun niyẹn.

O ni Isaac sọ pe ẹnikan yoo foun (Ṣeyi) ni majele jẹ, afi boun ba le sare ṣe awọn etutu kan.

Ẹyin tutu atawọn eroja mi-in ni Isaac sọ pe ki Ṣeyi lọọ ra wa kawọn sare fi ṣe iṣẹ iṣẹgun fun un, nitori bi ko ba tete ṣe bẹẹ, ewu nla ni.

Eyi ni Ṣeyi loun lọọ ra kiakia, nitori oun gba iran ti Isaac ri soun gbọ. O ni boun ṣe ra ẹyin naa de ni Isaac se e lori ina pẹlu awọn nnkan mi-in, o si gbe e foun pe koun jẹ ẹ.

Ṣeyi sọ pe boun ṣe jẹ asejẹ naa tan loun sun lọ fọnfọn. Asiko to sun naa ni Isaac bẹrẹ si i fi nnkan ọmọkunrin ẹ ṣere gẹgẹ bo ṣe wi, o fọwọ pa a titi tiyẹn fi da nnkan ọmọkunrin sara.

Atọ to da sara naa ni Isaac fi nnkan nu, to si tọju ẹ, nigba ti Ṣeyi yoo si fi ji loju oorun, kinni ẹ ko ṣiṣẹ mọ, niṣe lo rọ bii eweko tina mu, bi ọrọ ṣe di ariwo niyẹn.

Wọn fa a de teṣan ọlọpaa, awọn agbofinro si sọ pe awọn dokita lo le sọ boya nnkan ti ṣe kinni Ṣeyi ni ko fi dide.

Wọn ṣayẹwo fun un lati mọ boya kinni naa ṣi wa daadaa, ṣugbọn ayẹwo oyinbo fidi ẹ mulẹ pe nnkan ọmọkunrin Ṣeyi ko ṣiṣẹ mọ, iṣoro kan ti ba a.

Eyi lo fa a tawọn ọlọpaa fi tọju Isaac sahaamọ, ibẹ lo ṣi wa titi ta a fi pari akojọpọ iroyin yii.

CP Edward Ajogun ti paṣẹ pe ki wọn gbe e lọ si kootu fun igbẹjọ lori ẹsun kinni onikinni ti wọn ni oun lo mu un ọhun.

Leave a Reply