Lati ijẹta ni iroyin naa ti jade, awon oniroyin Sahara Reporters lo si gbe iroyin naa sita. Ohun ti wọn kọ sibẹ ni pe iyawo Aarẹ Orilẹ-ede yii, Aisha Buari, ti sa lọ si Dubai. Wọn lo sọ pe eto aabo Naijiria nibi ko dara to, bi eeyan ba si n wa ifọkanbalẹ, Dubai tabi ibomi-in ni yoo lọ. Ohun ti awọn eeyan wa n ro pe ko ṣẹlẹ ni pe nigba ti Sahara gbe iroyin naa jade, kia ni ileeṣẹ aarẹ, tabi awọn amugbalẹgbẹẹ iyawo Buhari nidii eto ikede ati iroyin yoo ti sare jade, ti wọn yoo si ni ko si ohun to jọ iru iroyin bẹẹ.
Ṣugbọn titi di asiko yii, ko sẹni to gbọ kinni kan lẹnu awọn eeyan iyawo Buhari, eyi to fi ẹsẹ ọrọ naa mulẹ pe o ṣee ṣe ko jẹ ootọ ni. Yatọ si pe ko sẹni kan to gburoo rẹ nigboro, tabi nibikibi laarin Naijiria lati bii ọjọ meloo kan wa, ti ko si sẹni to gbo ko sọrọ si gbogbo ohun to n lọ niluu, paapaa lasiko ti wọn ji awọn ọmọleewe bii irinwo gbe lọsẹ to kọja, awọn Sahara Reporters royin pe lati inu oṣu kẹsan-an ti obinrin naa ti ṣe iyawo fun ọmọ rẹ ninu Aso Rock, lati igba naa lo ti pada si Dubai, ko si ti i fẹsẹ tẹ Naijiria lati igba yẹn.
Awọn oniroyin naa ni bo tilẹ jẹ oṣu kẹta ree ti obinrin yii ti kuro nile, ko ti i mura rara lati pada wa, nitori o ni ilu yii ko ni eto aabo to dara to. Lati igba ti iṣẹlẹ kan ti waye ninu oṣu kẹfa ọdun yii, ti wọn ti yinbọn funra wọn ninu Aso Rock, ni Aisha ko ti ni ifọkanbalẹ taara ninu ile ijọba naa mọ, bo si ti ṣeyawo fun ọmọ rẹ lo ti jade, ti ko si boju wẹyin rara.
Gbogbo akitiyan Alaroye lati gbọ lati ẹnu awọn ti wọn n ba iyawo Aarẹ naa ṣiṣẹ ni ko so eeso rere, nitori “Loootọ ni ko si nile” nikan lọrọ ti ẹni to ba wa sọrọ sọ, ṣugbọn ko sọ ibi ti o lọ, tabi igba to ti lọ, tabi igba to fẹẹ de fun wa.
Ọpọ eeyan ni wọn n sọ pe loootọ lawọn ko ri obinrin naa nita mọ, ti awọn ko si gbọrọ lẹnu rẹ, boya bi ọrọ ṣe waa fẹe di ariwo yii, iyawo Buhari yoo tun jade si gbangba, tabi ko sare wale lati Dubai.