N’ILE-IFẸ, WỌN NI JUBIRILA J’IYAWO ONIYAWO GBE TỌMỌTỌMỌ

Wọn ti wọ ọkunrin kan to n jẹ Jubril Anifowoṣe lọ sile-ẹjọ ni Ile-Ifẹ o. Lanaa ode yii ni o. Ẹsun pe o ji iyawo oniyawo gbe tọmọtọmọ lo sọ ọ dero iwaju adajọ majisireeti ipinlẹ Ọṣun naa. Kẹmi, iyawo Dọtun Ẹlufidipẹ, ni wọn ni Jubri ji gbe sa lọ pẹlu awọn ọmọ rẹ meji.

Olupẹjọ ijọba, Abdullahi Emannuel, sọ pe alajọgbe ni Jubril ati awọn Ẹlufidipẹ ni ojule kẹẹdogun, Popo Ẹnu-Ọwa ni Ile-Ifẹ, o si mọ pe iyawọ Dọtun ni Kẹmi, a si fi bo ṣe palẹ obinrin naa mọ lọdun 2016 pẹlu awọn ọmọ rẹ. Olupẹjọ naa ni ohun  ti Jubril ṣe yii lodi si ofin ipinlẹ Ọṣun ti ọdun 2002, ati pe iwa to le da ilu ru gan-an ni.

Jubril naa kuku wa nibẹ ti wọn fi n rojọ yii mọ ọn lẹsẹ, n lo ba dide to loun ko jẹbi ẹsun ijinigbe ti wọn n fi kan oun yii rara. Agbẹjọro rẹ paapaa dide, iyẹn Arabinrin E. O. Lawal, o ni ki wọn tiẹ kọkọ gba beeli onibaara oun yii na, ko too di pe awọn yoo maa ba ẹjọ naa lọ.

N ni Adajọ A. A. Adebayọ ba gba beeli ọkunrin yii, ṣugbọn yoo ni oniduuro kan ti yoo ni egbẹrun lọna ọgọrun-un Naira, nitori aibaamọ, o si sun igbẹjo naa siwaju di ọgbọnjọ oṣu yii.

Pẹlu bi igbẹjọ ọhun ṣe n lọ, ohun ti Jubril saa n tẹnu mọ ni pe, ‘Emi o jiyawo oniyawo gbe ni temi o!’

Leave a Reply