Wọn ni Korona pa ọga agba Fasiti Eko tẹlẹ, Ibidapọ-Obe

Faith Adebọla, Eko

Iroyin buruku kan to gbode lalẹ ọjọ Aiku, Sannde yii, ni ti Ọga agba Fasiti Eko, University of Lagos, nigba kan, Ọjọgbọn Oyewusi Ibidapọ-Obe, to dagbere faye.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, wọn ni arun aṣekupani nni, Koronafairọọsi lo gbẹmi baba ẹni ọdun mọkanlelaaadọrin naa.

Ibidapọ-Obe, titi di asiko tọlọjọ de yii, ni Ọga agba ati Alaga ẹgbẹ awọn akọṣẹmọṣẹ fasiti akọkọ ni Ibadan. Akọwe ẹgbẹ ọhun, Ọlayinka Balogun, lo kede ipapoda ogbontarigi ọmọwee naa.

Wọn ni lati bii ọjọ diẹ sẹyin ni baba naa ti n gba itọju pajawiri fun aisan Korona to lugbadi ẹ laipẹ yii

Leave a Reply