Wọn ni Korona tun pa aburo igbakeji gomina Eko

Faith Adebọla, Eko

Lẹyin ọjọ mẹta ti iku ojiji pa Ọjọgbọn Ibidapọ-Obe, arun aṣekupani buruku nni, Koronafairọọsi, ti tun ṣọṣẹ nla mi-in nipinlẹ Eko lọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, pẹlu bi wọn ṣe lo pa Dokita Haroun Hamzat, aburo Igbakeji gomina ipinlẹ Eko, Dokita Kadri Ọbafẹmi Hamzat.

ALAROYE gbọ pe ko ti i pe ọsẹ kan tan tọkunrin ẹni ọdun mẹtadinlogoji ọhun lugbadi arun buruku yii, to si bẹrẹ si i gba itọju nibi iyasọtọ kan, ko too di pe ọlọjọ de lalẹ ọjọ Iṣẹgun ọhun.

Titi dasiko iku rẹ, Dokita Hamzat ni ọga agba ọkan lara awọn ileewosan ijọba (Primary Health Centre) to wa labẹ ijọba ibilẹ onidagbasoke Orile Agege (LCDA).

Ninu atẹjade kan ti ẹgbẹ awọn onimọ iṣẹgun oyinbo (Nigeria Medical Association), ẹka ti Eko, kọ lati fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, wọn daro iku ọkan lara wọn lọ yii, wọn si kẹdun pẹlu awọn mọlẹbi oloogbe naa.

Wọn ni ọkunrin naa ti ṣe bẹbẹ lẹka imọ iṣegun oyinbo, o si ti mu iyatọ ba iṣẹ itọju iṣegun lawọn ileewosan alabọọde to wa labẹ akoso rẹ ni kansu Orile Agege ọhun. Wọn royin rẹ gẹgẹ bii alaapọn ti ki kẹrẹ nidii iṣẹ rẹ.

Wọn gbadura pe k’Ọlọrun tu awọn mọlẹbi, ọrẹ, alabaaṣiṣẹ ati awọn oṣiṣẹ ẹka iṣegun ninu fun adanu nla ti ipapoda Dokita Haroun Hamzat yii mu wa.

Leave a Reply