Wọn ni nitori Sunday Igboho l’Ọbasanjọ ṣe sabẹwo si ilẹ Olominira Benin

Faith Adebọla

 Iroyin to n ja ranyin lori atẹ ayelujara lasiko yii ni ti igbesẹ pataki ti ọkan ninu awọn agbaagba to lookọ nilẹ Yoruba, to tun jẹ Aarẹ orileede yii nigba kan, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, gbe lori ọrọ Sunday Adeyẹmọ tawọn eeyan mọ si Sunday Igboho, Ọbasanjọ ati Aarẹ orileede Bẹnẹ, Ọgbẹni Patrice Talon, ti tilẹkun mọri ṣepade lori ọrọ ọhun.

Laarin ọsẹ akọkọ ninu oṣu kẹjọ yii l’Ọbasanjọ gbera irinajọ lọọ siluu Zanzibar, lorileede Tanzania, fun apero pataki kan, wọn ni bo ṣe n dari bọ, ilu Port-Novo, ti i ṣe olu-ilu ati ibujokoo ijọba orileede Olominira Benin lo balẹ si, taara lo si lọọ ṣabẹwo si Aarẹ wọn lọhun-un.

Ba a ṣe gbọ, wọn l’Ọbasanjọ kọkọ lo anfaani naa lati ba Aarẹ ilẹ Bẹnẹ tẹlẹ ri, Ọgbẹni Nicephore Soglo, kẹdun ti iyawo rẹ, Roseline Soglo, to doloogbe lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu keje, to kọja yii.

Bo tilẹ jẹ pe ko sẹni to mọ hulẹhulẹ ọrọ tawọn agbaagba meji naa ba ara wọn sọ labẹ aṣọ, Amugbalẹgbẹẹ fun Ọbasanjọ lori eto iroyin, Ọgbẹni Kẹhinde Akinyẹmi, ti fidi ẹ mulẹ pe loootọ lọga oun tilẹkun mọri ṣepade pẹlu Aarẹ ilẹ Bẹnẹ, ṣugbọn oun o le sọ ju bẹẹ lọ lasiko yii na.

Amọ ṣa, Akọwe ẹgbẹ Afẹnifẹre, Ọgbẹni Kọla Ọmọlolu, ti sọ pe ẹgbẹ naa n ṣiṣẹ ni ifọwọsowọpọ pẹlu Baba Ọbasanjọ, lori ọrọ Sunday Igboho, ati pe didun lọsan yoo so laipẹ.

“Ẹ jẹ ki n sọ fun yin ni taarata pe ẹgbẹ Afẹnifẹre ati aarẹ ana, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ jọ n ṣiṣẹ papọ lati da ireti awọn ọmọ Naijiria pada, paapaa awọn ọmọ Oduduwa, o si daju pe aṣeye lalakan yoo ṣ’epo lori ọrọ yii.”

 

Leave a Reply