Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Gbogbo akitiyan awọn oṣiṣẹ panapana lati le ri awọn ọmọdebinrin meji ti iya wọn ju sinu kanga lalẹ ọjọ Aje, Mọnde, yọ jade lo ja si pabo latari bi omi ṣe kun inu kanga naa bamubamu.
Iya awọn ọmọ naa, ẹni ti gbogbo eeyan mọ si Ọmọwumi, la gbọ pe laipẹ yii lo de lati orileede kan to lọ, to si jẹ pe latigba to ti de lo ti n ṣe gan-an-gan-an-gan kaakiri.
Nigba to di alẹ ọjọ Aje, Mọnde, la gbọ pe obinrin to n gbe lagbegbe Anjọọrin, laduugbo Kọledowo, niluu Oṣogbo, ko awọn ọmọ rẹ mejeeji naa, to si ju wọn sinu kanga.
Orukọ awọn ọmọ naa ni Nimisire Saka, ọmọ ọdun mẹjọ, ati Darasimi Saka, toun jẹ ọmọ ọdun marun-un.
Aarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ti awọn araadugbo mọ nnkan to ṣẹlẹ ni wọn lọọ fi ọrọ naa to ileeṣẹ panapana ati awọn ọlọpaa agbegbe naa leti.
A gbọ pe lẹyin ti wọn ṣe wahala ti wọn ko si ri oku awọn ọmọ naa gbe jade ni awọn ọlọpaa mu obinrin naa lọ sagọọ wọn.
Alukoro fun ileeṣẹ panapana nipinlẹ Ọṣun, Ibrahim Adekunle, sọ pe lati alẹ ọjọ Aje lobinrin ọhun ti ju awọn ọmọ naa sinu kanga, ṣugbọn ọjọ Iṣẹgun lawọn araadugbo fi to ileeṣẹ wọn leti.
Adekunle sọ siwaju pe omi inu kanga naa pọ, idi niyẹn ti wọn ko fi ri awọn ọmọ ọhun gbe jade.
Bakan naa ni Alukoro ọlọpaa, SP Yẹmisi Ọpalọla, sọ pe awọn ti mu obinrin naa sọdọ, iwadii si ti bẹrẹ lori ọrọ naa.