Faith Adebọla
Titi di ba a ṣe n sọ yii ni awọn eeyan adugbo Iwo Road, niluu Ibadan, nibi ti awọn onimọto ti lọọ kọju ija si awọn to n ta foonu ni Shopping Complex kan niluu naa lori pe wọn ko ja tikẹẹti.
ALAROYE gbọ pe ọrọ tikẹẹti ti wọn ni awọn to n ta foonu nileetaja naa kọ lati ja ni awọn Park Management System, labẹ idari ọga awọn onimọto tẹlẹ, Ọgbẹni Mukaila Lamidi, ti gbogbo eeyan mọ si Auxilliary fi bẹrẹ wahala pẹlu wọn.
Asiko ti wahala naa n lọ lọwọ ni wọn ni ọmọkunrin yii, Rahmon Azeez, ti ko ju ẹni ọdun mẹtadinlogoji lọ ati ẹgbọn rẹ torukọ rẹ n jẹ Hammed jọ fẹẹ wa mọto wọle.
Ṣugbọn awọn ti wọn n fa wahala naa ti fi mọto kan di oju ọna. Lasiko ti ọkunrin naa n sọ fun wọn pe ki wọn gbe mọto kuro loju ọna ki awọn le raaye wọ inu ọgba naa ni wahala bẹrẹ, ki awọn to wa nibẹ si too mọ ohun to n ṣẹlẹ, wọn ti yinbọn fun ọmọkunrin ti wọn ni ilu oyinbo lo ti kawe yii.
ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii ọdun mẹta sẹyin ni iyawo rẹ bi ibeji niluu oyinbo, ti wọn si ṣe ikomọ awọn ọmọ naa ni Naijiria. Latigba naa ni ọmọkunrin yii ti n gbidanwo lati lọ siluu oyinbo ko le lọọ ba awọn mọlẹbi rẹ.
Ọsẹ bii meji sẹyin ni awọn to mọ ọmọkunrin naa daadaa sọ pe wọn ṣẹṣẹ fun un ni fisa, to si ti n palẹmọ lati lọọ ri iyawo atawọn ọmọ rẹ ki wọn too fiku ojiji pa a yii.
Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Seyi Makinde, ṣabẹwo si Iwo Road ti iṣẹlẹ naa ti waye l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ṣugbọn niṣe ni awọn eeyan fariwo bọnu, ti wọn n bu gomina naa, ti ọpọ si n pariwo pe awọn ko fẹ PMS, iyẹn ileeṣẹ ti gomina da silẹ pe ki wọn fi maa gbowo lọwọ awọn ọlọja, onimọto ati ọlọkada.
Bakan naa ni wọn naka abuku si Mukaila ti gbogbo eeyan mọ si Auxilliary ti gomina fi ṣakoso ileeṣẹ naa, wọn ni ọkunrin naa lo ko awọn eeyan wa si awọn ṣọọbu ti wọn ti fa wahala naa.