Wọn ni pasitọ Ridiimu atawọn oṣiṣẹ rẹ mejilelogun wa ninu awọn ti ile wo pa n’Ikoyi

Jọkẹ Amọri

O ti di eeyan mejilelogun ti wọn ri oku wọn yọ ninu ijamba ile to wo niluu Ikoyi, nipinlẹ Eko, lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.

Ṣugbọn pẹlu rẹ naa, wọn ko ti i ri pasitọ ijọ Ridiimu kan ti wọn porukọ rẹ ni Ọla Ogunfuwa atawọn mọkanlelogun mi-in ti wọn ti wọn jẹ ọmọọṣẹ rẹ.

Gẹgẹ bi iweeroyin Punch ṣe ṣalaye, wọn ni Ogunfuwa to jẹ oluṣọagutan ijọ Ridiimu ti wọn n pe ni Living Water Parish, to wa niluu Ibafo, nipinlẹ Ogun, wa ninu awọn agbaṣẹṣe to n ṣiṣẹ nibi ile to wo ọhun. O wa nibẹ lasiko iṣẹlẹ yii, ko si sẹni to ti i gburoo rẹ nibikibi, bẹẹ ni ko ti i si ninu awọn oku ti wọn ti ko jade ninu ile naa.

Ọkan ninu awọn ọrẹ ọkunrin naa ti wọn porukọ rẹ ni Ọmọtọsho Ṣọla Emmanuel ṣalaye fun akọroyin Punch pe Ogunfuwa atawọn oṣiṣẹ rẹ bii mejilelogun lo wa labẹ ile to wo yii. O ṣalaye pe Ẹnijinnia ni ọkunrin yii, o si tun jẹ agbaṣẹṣe. O ni awọn ọmọ iṣẹ rẹ, ninu eyi ti birikila, wẹda atawọn oniṣẹ ọwọ bẹẹ wa ni wọn tẹle ọkunrin naa wa si Ikoyi ti wọn ti n ṣiṣẹ yii lati ilu Ibafo.

Ọmọtọsho ni lati ọjọ Aje, Mọnde, ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ ti wọn si ti n yọ awọn eeyan jade, oun ko ti i ri pasitọ yii tabi eyikeyii ninu awọn oṣiṣẹ to ko lọ.

O ni awọn to wa nibẹ lasiko iṣẹlẹ naa sọ pe pasitọ yii jade lasiko ijẹun, oun naa fẹẹ lọọ jẹun. Wọn ni bo ṣe n fọwọ rẹ pe ki oun le lọọ jẹun ni ọkan ninu awọn ọga rẹ pe e, to si pada wọnu ile. Ko ju iṣẹju marun-un si mẹwaa lẹyin eleyii ti ile naa da wo, oun naa si wa ninu rẹ pẹlu awọn oṣiṣẹ rẹ yii ati awọn mi-in.

O ni iyanu Ọlọrun ni awọn n gbadura fun lori awọn ti wọn wa labẹ ile to da wo yii.

Bẹ o ba gbagbe, ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni ile alaja mọkanlelogun naa da wo ni Ikoyi,  to si ṣeku pa ọpọ eeyan, bẹẹ ni wọn si n lakaka lati yọ awọn mi-in ti wọn tun ha sinu ile naa.

 

Leave a Reply