Wọn ni Suliya atọrẹ ẹ fẹẹ pa Gomina Oyetọla l’Oṣogbo, ladajọ ba ju wọn sẹwọn

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Lori ẹsun pe wọn gbiyanju lati pa Gomina ipinlẹ Ọṣun, Adegboyega Oyetọla, lasiko iwọde SARS, adajọ ile-ẹjọ Majisreeti kan niluu Oṣogbo, ti ju awọn ọmọbinrin meji kan; Suliyat Tajudeen ati Ayọmide Abdulazeez, sẹwọn.

Suliyat, ẹni ogun ọdun ati Ayọmide, toun naa jẹ ẹni ogun ọdun ni Agbefọba, John Idoko, ka ẹsun mẹfa si lọrun.

Lara awọn ẹsun naa ni igbiyanju lati paniyan, biba nnkan jẹ, ole jija, fifọ ile onile ati dida omi alaafia agbegbe ru.

Awọn mejeeji ni wọn sọ pe awọn ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan awọn, bẹẹ ni agbẹjọro wọn, Nurudeen Kareem bẹbẹ fun beeli wọn.

Adajọ Dokita Oluṣẹgun Ayilara sọ pe ki awọn mejeeji maa lọ sọgba ẹwọn ilu Ileṣa titi di ogunjọ, oṣu kọkanla, tigbẹjọ yoo tun waye lori ọrọ wọn.

Leave a Reply