Wọn ni Wolii Sẹlẹ lu awọn eeyan ni jibiti owo nla l’Ọbada-Oko

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Atimọle ọlọpaa lobinrin wolii Ṣẹlẹ kan, Purofẹtẹẹsi Okuwakẹmi Ṣotọnọde (Marcellus), wa bayii l’Abẹokuta. Awọn ọlọpaa sọ pe o pẹ to ti n lu awọn eeyan ni jibiti owo nla l’Ọbada oko to kọ ṣọọṣi rẹ, Marvelous Model Parish, Ọbádá-Oko, si.

Wolii to fẹran oge ṣiṣe yii ti wa ninu awọn tọlọpaa n wa tipẹ gẹgẹ bi Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyẹmi, ṣe wi.

O ṣalaye pe ẹnikan to n jẹ Idris Iliyas lo kọkọ mu ẹsun Wolii ti wọn tun n pe ni Marvelous yii wa, okuta kan ti wọn n pe ni Kaolin lobinrin yii bẹ Idris pe ko ba oun ta fún ileeṣẹ kan, iyẹn si ko okuta naa lọ fun wọn.

Ṣugbọn niṣe ni iya yii gbẹyin lọ sileeṣẹ naa, to si gba miliọnu kan ati ẹgbẹrun lọna igba naira (1.2m) ti i ṣe owo to yẹ ki Idris gba fun okuta to ko lọ. Eyi waye loṣu kọkanla, ọdun 2019.

Yatọ si eyi, ni ọgbọnjọ, oṣu kẹsan-an, ọdun 2020 yii, Ṣotọnọde gba ẹgbẹrun lọna igba naira (200,000) lọwọ ẹnikan ti wọn pe orukọ ẹ ni Ọlabangboye Olalekan. Ilẹ pulọọti kan lo ni oun yoo ta fun iyẹn l’Ọbada-Oko. Ṣugbọn alọ owo yii ni Ọlalekan ri, ko ri abọ ẹ, Purofẹtẹẹsi ko fun un nilẹ, bẹẹ ni ko da owo pada.

Ninu oṣu kẹrin, ọdun yii, ni wọn ni obinrin yii gba ẹgbẹrun lọna ọọdunrun naira (300,000) lọwọ Kẹhinde Ọjẹkunle, to ni kiyẹn naa ko okuta Kaolin lọ sileeṣẹ kan, ṣugbọn to jẹ niṣe lo tun gba ẹyin lọọ gbowo iṣẹ naa, to si da a sapo.

Wọn lo tun lu Gbọlagade Damilọla naa ni jibiti ẹgbẹta le laadọrin naira (670,000), nigba to gbowo lọwọ iyẹn naa pe oun yoo ta ogoji apo irẹsi fun un.

Alukoro sọ pe Wolii Marvelous yii ti n sa kiri tipẹ, nítorí awọn jibiti to lu yii, awọn pẹlu si ti n wa a latigba ti awọn eeyan ti n mu ẹjọ rẹ wa, ko too waa di pe ọwọ ba a lọjọ kẹfa, oṣu kẹwaa yii, nibi to fara ṣoko si.

Nigba tawọn ọlọpaa fọrọ wa a lẹnu wo, Marvelous jẹwọ pe loootọ loun lu awọn eeyan mẹrin naa ni jibiti owo, ṣugbọn ko le ṣalaye gidi lori ohun to fowo ọhun ṣe.

Ọga ọlọpaa nipinlẹ Ogun, CP Edward Ajogun, ti ni ki wọn wadii wolii yii daadaa, ki wọn si gbe e lọ sile-ẹjọ laipẹ rara.

Leave a Reply