Wọn pa Adebari si yara ẹ, wọn tun ge ọwọ osi ẹ lọ l’Abẹokuta 

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, lawọn agbebọn kan ya wọ Ojule kẹrin, Opopona Tinubu, Oke-Ṣokori, l’Abẹokuta. Wọn gba foonu awọn araale naa,  ṣugbọn niṣe ni wọn yinbọn pa Ọlayiwọla Adebari, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn, wọn si ge ọwọ rẹ osi lọ.

Ẹnikan to ba wa sọrọ lori iṣẹlẹ naa ṣalaye pe nnkan bii aago kan aabọ oru ọjọ Aiku naa lawọn mẹrin kan ti wọn gbebọn dani ya bo ile naa.

 

O ni bi wọn ti de ni wọn n wọ yara si yara, ti wọn ko jinni jinni bo awọn araale naa, ti wọn si n gba foonu wọn.

Okunrin ti ko darukọ rẹ yii sọ pe nigba ti wọn de yara Adebari, niṣe ni wọn yinbọn pa a, bẹẹ wọn o yinbọn ninu awọn yara yooku ti wọn ti kọkọ wọ.

Yatọ si pe wọn yinbọn ni yara Adebari, ti wọn si pa a, nigba tawọn agbebọn ọhun lọ tan lawọn araale ri i pe ihooho gedegbe ni wọn sọ ọmọkunrin naa si, wọn si ti ge ọwọ rẹ osi lọ.

Apẹẹrẹ ti wọn fi silẹ pẹlu ọwọ ti wọn ge lọ yii lo jẹ kawọn eeyan maa sọ pe o ṣee ṣe ko jẹ pe ọmọ ẹgbẹ okunkun ni Adebari, wọn ni awọn ti wọn ti jọ da nnkan pọ ri ni wọn waa da sẹria iku fun un.

Awọn araale fiṣẹlẹ yii to awọn ọlọpaa teṣan Ibara leti, awọn ni wọn waa gbe oku naa lọ si mọṣuari Ọsibitu Jẹnẹra to wa n’Ijaye, l’Abẹokuta.

DSP Abimbọla Oyeyẹmi ti i ṣe Alukoro ọlọpaa Ogun fidi iṣẹlẹ yii mulẹ l’Ọjọruu, ọjọ kẹjọ, oṣu kejila yii. O ni ọmọ ẹgbẹ okunkun lawọn to pa Adebari, awọn si ti bẹrẹ iwadii lori wọn.

 

Leave a Reply