Wọn pa Fulani darandaran sinu oko, wọn tun ge ẹya ara rẹ lọ ni Kwara 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Awọn afurasi afini soogun owo ti ṣeku pa Fulani darandaran ẹni ogun ọdun, Usman Audu, niluu Igosun, ijọba ibilẹ Ọffa, nipinlẹ Kwara, ti wọn si tun ge awọn ẹya ara rẹ kan lọ.

Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọṣẹ yii, ni ẹgbọn Audu mu ẹsun lọ si agọ ọlọpaa pe Audu fi awọn maaluu jẹ koriko lọ lati aago mọkanla owurọ Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ to kọja yii, awọn maaluu nikan ni wọn dari wale laṣaalẹ ọjọ naa, Audu ko pada wale, eyi lo mu ki awọn ẹsọ alaabo fọn sinu igbo lati wa ọkunrin ọhun jade. Ṣugbọn oku rẹ ni wọn ba ninu oko kan ni agbegbe naa, ti wọn si ti yọ ọkan rẹ (heart), oju ara ati oju rẹ mejeeji lọ.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, ẹka ti ipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Ọkasanmi Ajayi, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni awọn o ti i ri afurasi kankan mu, ṣugbọn iwadii ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ ọhun. O tẹsiwaju pe wọn ti gbe oku Audu lọ si yara igbokuu-si nileewosan ijọba to wa   niluu Ọffa.

 

Leave a Reply