Wọn pa ọmọ sẹnetọ ilẹ wa sinu ile ẹ, niṣe ni wọn yin in lọrun pa

Inu ibanujẹ nla ni ọkan ninu awọn sẹnetọ ilẹ wa lati ipinlẹ Kebbi, Bala Na Allah, wa bayii pẹlu bi awọn eeyan kan ti ẹnikẹni ko ti i mọ ṣe lọọ ka ọkan ninu awọn ọmọ rẹ, Abdulkarim Bala Ibn Na’Allah, ẹni ọdun mẹrindinlogoji mọle, ti wọn si fun un lọrun pa.

ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago mejila ọsan ni wọn wọ ile ọmọkunrin to n ṣiṣẹ awọn to n wa baalu naa to wa ni Umara Gwandu Road, Malali, niluu Kaduna, ti wọn so o lokun, ti wọn si yin in lọrun pa sibẹ lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹjọ yii.

Gẹgẹ bi Oludamọran pataki fun sẹnetọ naa to jẹ baba ọmọ yii, Garba Mohammed, to fidi iroyin naa mulẹ fun iweeroyin Daily Trust ṣe sọ, o ni ori aja ile to wa lẹyin ile ọmọkunrin naa ni wọn gba wọle, ti wọn si gba inu silin (ceiling) ile rẹ naa wọ ọdọ ọmọ sẹnetọ yii ti wọn fi pa a.

Mohammed ni ọkan ninu awọn ọdẹ to n ṣọ adugbo naa lo ri ilẹkun ile ọmọkunrin yii ni ṣiṣi silẹ, to si pe akiyesi awọn aladuugbo si i, nigba ti wọn yoo wọle Abdulkarim ni wọn ba oku rẹ nibẹ.

Ọmọkunrin mẹta ni wọn ni Sẹnetọ to n ṣoju awọn eeyan agbegbe Guusu Kebbi yii ni, ti awọn mẹtẹẹta si n ṣiṣẹ awọn to n wa baaluu.

Leave a Reply