Wọn paayan meji, wọn ṣe ọpọ agbofinro leṣe ninu ija Fúlàní ati Yorùbá ni ipinlẹ Ọyọ

Eeyan meji ku, wọn ṣe ẹṣọ Amọtẹkun leṣe nibi ija Fulani ati Yoruba l’Ọyọọ
Ọlawale Ajao, Ibadan
Eeyan meji lo ku lasiko ija to waye laarin awọn Fúlàní ati Yorùbá laarin ọja kan to wa labule kan ti wọn n pe ni Àbá Àbúgúgù, nijọba ibilẹ Atisbo, nipinlẹ Ọyọ.
Bakan naa láwọn oṣiṣẹ awọn ikọ agbofinro ipinlẹ Ọyọ ta a mọ sí Amọtẹkun atawọn ọdẹ ilu ta a mọ sí fijilante fara pa yannayanna.
Orúkọ meji ninu awọn oṣiṣẹ ikọ Amọtẹkun to fara ṣèṣe ni Michael Oguntade ati Yekini Tijani.
Ṣugbọn a kò ti i mọ orúkọ àwọn fijilante to fara gba ninu iṣẹlẹ ọhun.
Bó tilẹ jẹ pé a ko ti i mọ ohun tó fa laasigbo naa, ija ọhun lawọn agbofinro wọnyi n gbiyanju lati pẹ̀tù sí ti meji ninu wọn fi kú, ti ọpọ awọn yooku si fara pa  yanna-yanna.
Nigba to n fìdí iṣẹlẹ yii mulẹ, oludari ìkọ Amọtẹkun nipinlẹ Ọyọ, Ajagun-fẹyinti Ọlayinka Ọlayanju, sọ pe “Fulani kan ati ọmọ Yorùbá kan ni wọn n já lọjọ Aje, Mọnde, to kọja. Ija yẹn láwọn eeyan wa n pari ti ọkan ninu awọn Fúlàní to wa nibẹ fi ṣa wọn ladaa. O ṣa ọkan ladaa lori, o ṣa ekeji ladaa léjìká.
Eyi lo jẹ kí àwọn Amọtẹkun yooku sáré gbe awọn meji ti wọn fara gbọgbẹ́ lọ si ọsibitu fún itọju nigba ti awọn to n já ṣi n ba ija wọn lọ.
Ajagunfẹyinti Ọlayanju fìdí ẹ̀ múlẹ̀ siwaju pe eeyan meji lo j’Ọlọrun nipe nibi iṣẹlẹ ọhun, ṣugbọn oun ko le sọ irú èèyàn tí wọn jẹ.

Leave a Reply