Wọn ri ileeṣẹ to n rọ ibọn AK-47 ni Jos

Faith Adebọla

Ileeṣẹ ọlọpaa ti ṣafihan awọn afurasi ọdaran meji kan, Joe Micheal ati Iliya Bulus, wọn lawọn mejeeji ni wọn wa lẹyin ileeṣẹ to n rọ ibọn oyinbo AK-47 nilẹ wa, inu igbo kijikiji kan nilu Jos, ipinlẹ Plateau, ni wọn kọ ileeṣẹ naa si.

Ilu Abuja, olu-ilu ilẹ wa, ni wọn ti ṣafihan awọn afurasi ọdaran mejeeji ọhun l’Ọjọruu, Wẹsidee yii, wọn lawọn ọtẹlẹmuyẹ to n ba ikọ ọlọpaa IRT (Intelligence Response Team) ati STS (Special Tactical Squad) ṣiṣẹ ni wọn ṣawari ileeṣẹ naa.

Alukoro apapọ fawọn ọlọpaa, Ọgbẹni Frank Mba ṣalaye pe o ya awọn agbofinro lẹnu lati ri i pe ibọn agbelẹrọ naa ko fi bẹẹ yatọ seyii ti wọn n ko wa latilu oyinbo, o ni oriṣiiriṣii atamatase ibọn ni wọn n rọ nibẹ, o si da awọn loju pe awọn onimọ ẹrọ kan lo maa wa nidii idasilẹ ileeṣẹ ọhun.

Mba ni awọn ibọn tawọn ba nileeṣẹ naa dọgba pẹlu awọn ibọn AK-47 tawọn ajinigbe, adigunjale, janduku atawọn afẹmiṣofo n gbe kiri, o si da awọn loju pe ileeṣẹ yii wa lara ohun to jẹ kibọn pọ lọwọ awọn ọdaran kaakiri ilẹ wa.

Mba ni, “Tẹ ẹ ba wo awọn nnkan ija wọnyi, teeyan o ba kẹkọọ nipa ilo ibọn, tọhun o le mọ iyatọ laarin ibọn AK-47 ti wọn n ta niluu oyinbo ati eyi ti wọn ṣe yii, tori wọn jọra debii pe akolo ọta ati ọta kan naa ni wọn n lo.

“A ti bẹrẹ iwadii to lọọrin nipa iṣẹlẹ yii lati tubọ ri awọn to wa nidii okoowo buruku ọhun, a o si ni i jawọ titi tọwọ ofin fi maa to gbogbo wọn.”

Micheal, ọkan lara awọn tọwọ ba ọhun, jẹwọ pe kọlẹẹji ẹkọṣẹ ọwọ kan loun ti kawe jade niluu Jos, o ni ọdun kẹta toun ti wa lẹnu iṣẹ rirọ ibọn ree, ibọn ṣakabula loun kọkọ fi bẹrẹ koun too mọ nipa bi wọn ṣe n rọ AK-47 toun si bẹrẹ si i rọ iyẹn naa. O lo ti ju ọgọjọ ibọn lọ toun ti ṣe. O lọgaa oun kan to n jẹ James lo kọ oun niṣẹ, ṣugbọn o ti doloogbe bayii.

O tun jẹwọ pe niṣe loun n ta awọn ibọn naa, ẹgbẹrun lọna ọgọrin tabi ju bẹẹ lọ loun n ta ẹyọ kan.

Ṣa, Mba ni iwadii ṣi n tẹsiwaju, awọn si maa tuṣu ọrọ naa desalẹ ikoko.

Leave a Reply