Faith Adebọla
Ẹwọn oṣu mẹfa ni ọmọkunrin ti wọn porukọ ẹ ni Nuhu Zakari yii, yoo fi jura, ile-ẹjọ lo jẹbi ẹsun jibiti ori ẹrọ ayelujara ati ṣiṣe onigbọwọ fawọn ọmọ ‘Yahoo’, ti wọn fi kan an.
Adajọ Ṣẹrifat Ṣolebọ, ti ile-ẹjọ to n gbọ awọn ẹsun akanṣe (Special Offences Court) eyi to fikalẹ siluu Ikẹja, nipinlẹ Eko, lo gbe idajọ naa kalẹ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, o tun paṣẹ pe ki wọn sọ gbogbo dukia ti wọn gba lọwọ ọdaran naa di tijọba apapọ, o ni ijọba ti gbẹsẹ le e.
Ajọ to n fooro ẹmi awọn to n ṣe owo ilu mọkumọku ati awọn onijibiti ẹda nilẹ wa, Economic and Financial Crimes Commission (EFCC) lo wọ ọdaran yii lọ si ile-ẹjọ, ti wọn si fẹsun kan an.
Ninu alaye ti agbefọba, Ọgbẹni G. C. Akaogu ṣe, o ni inu oṣu kin-in-ni, ọdun yii, lọwọ ba Nuhu, atawọn ẹmẹwa rẹ kan, lagbegbe Lẹkki, Ajah, l’Erekuṣu Eko. O ni iṣẹ ọfintoto tawọn n ṣe ati olobo to ta ileeṣẹ naa lori iwa apamọlẹkun-jaye ati jibiti ẹrọ ayelujara ti wọn n ṣe lawọn fi mu wọn.
O lawọn ba foonu igbalode iPhone 7 kan, foonu Huawei ati kọmputa alaagbeletan kan lọwọ Nuhu lọjọ naa, awọn dukia yii ni wọn lọọ ṣayẹwo imọ ijinlẹ si, titi kan awọn ikanni ibanisọrọ rẹ bii Wasaapu, Fesibuuku atawọn mi-in, laṣiiri ba tu pe ọkunrin naa ti n ṣe agbodegba fawọn ọmọ ‘Yahoo’, wọn loun lo maa n ba wọn gba nọmba akaunti tawọn oyinbo n lo lati ilu oyinbo, to si n ṣe atare ẹ sawọn onijibiti ẹgbẹ ẹ ni Naijiria, ki wọn le ribi wọ owo olowo sa lọ.
Wọn tun tẹ gbogbo ifọrọ-ranṣẹ to ṣe lori Wasaapu jade, eyi si fidi ẹ mulẹ pe onijibiti ẹda kan lọdaran yii.
Ẹsun mẹrin ni wọn ti kọkọ fi kan Nuhu nigba ti wọn gbe e wa sile-ẹjọ tẹlẹ, ṣugbọn lẹyin to rawọ ẹbẹ si ajọ EFCC pe ki wọn ṣaanu oun, ki wọn din awọn ẹsun naa ku, oun ṣetan lati da awọn owo ati dukia toun fowo olowo ko jọ pada, eyi lo mu ki wọn din ẹsun rẹ ku si ẹyọ kan.
Ẹsun pe o jẹ onigbọwọ fawọn onijibiti nikan ni wọn waa fi kan an, bi ẹjọ naa si ṣe tun waye ni kootu, Nuhu ko tun fa ọrọ gun mọ, niṣe lo sọ pe oun jẹbi, oun o si ni arojare kankan mọ, ki adajọ ṣaanu oun loun bẹbẹ fun.
Adajọ Ṣolebọ ni iwa ọbayejẹ ni ọdaran yii jẹbi rẹ, ṣugbọn latari ẹbẹ to bẹ, ko lọọ gbatẹgun lọgba ẹwọn foṣu mẹfa pere, ko si sapa lati yi iwa buruku ọwọ pada to ba dẹni ominira.