Wọn sọ oṣiṣẹ ijọba to gba riba miliọnu marun-un sẹwọn ọdun mejila ni Kwara

Ibrahim Alagunmu, Ilorin

Ile-ẹjọ to ga ju lọ lorileede yii ti ju alaga igbimọ alaṣẹ tẹlẹ ri ni ile ẹkọ gbogbonise (Poly) ti ipinlẹ Kwara, Ọmọwe Saadu Alanamu, si ẹwọn ọdun mejila, fẹsun pe o gba riba miliọnu marun-un naira lọwọ agbaṣẹṣe ni ile ẹkọ ọhun.

Nibi igbẹjọ ti awọn igbimọ adajọ ẹlẹni marun-un jokoo rẹ ni ile-ẹjọ to ga ju lọ lorile-ede yii ti fidi ẹwọn ọdun mejila ọhun mulẹ, ti wọn si ni ko si idi ti wọn yoo fi da Alanamu silẹ, lẹyin to jẹbi ẹsun ti ajọ ICPC fi kan an lori iwa ibajẹ, ti ile-ẹjọ meji ọtọọtọ si ti ni ko lọọ fi aṣọ penpe roko ọba fun ọdun mejila gbako.

Ni ọdun (2017) ni wọn fi orukọ Alanamu sọwọ gẹgẹ bii ẹni ti yoo jẹ ọkan lara igbimọ ajọ ICPC, ṣugbọn nigba ti wọn ṣe iwadii rẹ ni wọn ri i pe o lẹbọ lẹru, wọn lo gba miliọnu marun-un owo riba lọwọ agbaṣẹṣe kan to fẹẹ gba iṣẹ akanṣe kan ni ile ẹkọ poli ipinlẹ Kwara to wa ni ilu Ilọrin.

Mahmud Abdulgafar lo ṣe idajọ Alanamu ni ile-ẹjọ giga ipinlẹ Kwara, to si ju ọmọwe naa si ẹwọn ọdun mejila, sugbọn o gba ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun lọ. Ile-ẹjọ ko-tẹmi-lọrun tun fidi ẹwọn ọdun mejila naa mulẹ, o ba tun gba ile-ẹjọ to ga ju lọ (Supreme) lọ.

Agbẹjọro rẹ, Ọjọgbọn Arẹmu Kannike, gbiyanju gbogbo agbara rẹ, ki Alanamu ma baa lọ ṣẹwọn, sugbọn pabo lo ja si, nitori ṣe ni adajọ ni ki Alanamu lọọ fi ẹwọn ọdun mejila jura.

Leave a Reply