Wọn sọ opopona kan lorukọ Anthony Joshua ni Ṣagamu

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

Bi ọmọ ẹni ba daa ka wi, ki i ṣe ka le baa fi i ṣaya. Nitori amuyangan ti abẹṣẹku-bii-ojo agbaye nni, Anthony Joshua, ọmọ bibi ilu Ṣagamu, jẹ ni alaga ijọba ibilẹ Ṣagamu, Ọgbẹni  Gbenga Banjọ, ṣe sọ opopona kan lorukọ ọdọmọde ẹlẹṣẹẹ naa bayii, to ni Anthony Joshua ni ọna naa yoo maa jẹ lae ati laelae.

Opopona tawọn eeyan mọ si Cinema Road tẹlẹ lo pada waa di Anthony Joshua bayii.

Nigba to n ṣalaye idi to fi sọ ona naa lorukọ ọkunrin ẹlẹṣẹẹ yii, Alaga Kansu Ṣagamu sọ pe lati mọ riri Joshua to jẹ ọmọ bibi Rẹmọ ni, nigba to jẹ awọn ami-ẹyẹ nla nla bii WBA, IBF, WBO, IBO lo ti gba. Iwuri ati idnuu lo ni o jẹ fun ilẹ Ṣagamu ti oloriire ọmọ naa ti jade wa.

O rọ awọn ọmọ bibi Ṣagamu lapapọ lati kọ iṣe Anthony Joshua, ki wọn jẹ ọmọ to ṣee fi yangan kari aye, ki wọn maa si dawọle ohunkohun to le takubu orukọ ilu nla naa.

Leave a Reply