Wọn tẹ eeyan mọkanlelọgbọn pa lasiko ti wọn fẹẹ lọọ gba ounjẹ ati ẹbun ọfẹ ni Port Harcourt

Ọrẹoluwa Adedeji

Eeyan bii mọkanlelọgbọn lawọn ọlọpaa sọ pe o ti pade iku ojiji ni ṣọọṣi kan ti wọn n pe ni King’s Assembly, Port Harcourt, nipinlẹ Rivers, lasiko ti wọn fẹẹ lọọ gba ounjẹ atawọn nnkan mi-in ti ijọ Ọlọrun naa fẹẹ fun awọn eeyan to ku diẹ kaato fun lawujọ lati ṣami ayẹyẹ ọdun kẹrin ti wọn da ijọ naa silẹ.
ALAROYE gbọ pe bo tilẹ jẹ pe aago mẹsan-an aarọ ni wọn fi eto naa si, lati nnkan bii aago mẹfa aabọ aarọ lawọn mi-in ti ya bo ibi ipade yii, nigba ti awọn kan tiẹ ti de silẹ lati ọjọ Ẹti, Furaidee, lati ri i pe ẹbun ati ounjẹ naa ko fo wọn ru.
A gbọ pe agbegbe GRA, niluu Port Harcourt, ni ṣọọṣi naa wa, ṣugbọn papa iṣere kan ti wọn ti n gba Polo ni wọn fi eto naa si pe yoo ti waye ko le baa gba awọn ero yii daadaa.
Awọn tọrọ yii ṣoju wọn sọ pe awọn kan ti wọn fẹẹ ṣe ere idaraya ninu ọgba ibi ti eto naa ti fẹẹ waye yii ni wọn ṣi geeti kekere to wa ninu ọgba naa ni tiwọn. Bi wọn ṣe ṣi geeti yii ni obitibiti ero bẹrẹ si i rọ gba ẹnu geeti kekere ti ko gba eeyan pupọ yii. Asiko ti onikaluku awọn ero naa si n tiraka lati raaye wọle ni awọn kan ṣubu lulẹ, ti awọn mi-in ninu awọn to fẹẹ wọle si tẹ wọn pa. Nigba ti oloju yoo si fi ṣẹ ẹ, eeyan mọkanlelọgbọn lo ti jẹ Ọlọrun nipe.
Ileeṣẹ redio kan ti wọn n pe ni Classic FM fidi ẹ mulẹ pe alaboyun kan atawọn ọmọ keekeeke mẹta wa ninu awọn to ba iṣẹlẹ naa lọ.
Adele Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Rivers, Grace Iringe-Koko, fidi ẹ mulẹ pe eeyan mọkanlelọgbọn lo ti ba iṣẹlẹ naa lọ. Bakan naa ni wọn ti ko ọpọ awọn to fara pa lọ si ileewosan ti wọn ko darukọ.

Leave a Reply