Wọn ti dajọ ẹwọn fẹni to dana sun Salome ni Kogi

Faith Adebọla

 

 

Ṣe ẹ ranti obinrin oloṣelu ọmọ ẹgbẹ PDP ipinlẹ Kogi ti wọn dana sun mọle lasiko rogbodiyan eto idibo sipo gomina lọdun 2019, wọn ti ran ẹni ti wọn lo jẹbi ipaniyan naa lẹwọn, ẹwọn ọdun mejila ati aabọ nile-ẹjọ ran an.

Onidaajọ A. Ajayi tile-ẹjọ giga ipinlẹ Kogi to gbe idajọ naa kalẹ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, sọ pe loootọ ni awọn ẹri to wa niwaju kootu naa fihan pe Ocholi jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan an. Lara awọn ẹsun naa ni igbimọ-pọ lati huwa buruku, idigunjale, didana sun dukia ẹni ẹlẹni ati ipaniyan abẹle.

Mẹfa lawọn afurasi ọdaran tawọn ọlọpaa kọkọ mu, ti wọn si ko wọn dele-ẹjọ, ṣugbọn bi igbẹjọ ṣe n lọ lọwọ ni wọn n yọ okun ẹjọ lọrun wọn lọkọọkan titi to fi ku ẹni kan ti wọn ṣedajọ rẹ yii.

Bo tilẹ jẹ pe afurasi ọdaran naa loun o ba awọn ọlọpaa sọrọ kan, oun o si kọ ọrọ kan silẹ ni teṣan wọn, sibẹ, wọn lo jẹwọ pe loootọ lawọn akọsilẹ tawọn ọlọpaa ka nipa ipa to ko ninu ninu bi wọn ṣe da ẹmi Abilekọ Abuh legbodo, waye, o si gba pe oun jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan an.

Satide, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kọkanla, ọdun 2019, ni eto idibo si ipo gomina waye nipinlẹ Kogi, eto naa ko si lọ nirọwọ-irọsẹ rara latari bawọn janduku ṣe ṣakọlu sawọn dukia ati eeyan titi kan awọn oṣiṣẹ eleto idibo lawọn wọọdu ati ibudo idibo kọọkan.

Ọsan ọjọ kẹta, ọjọ kejidinlogun, oṣu naa, lawọn janduku kan lọọ sọ ina sile Abilekọ Abuh to jẹ oun ni aṣaaju awọn obinrin (Women Leader) fẹgbẹ oṣelu People’s Democratic Party nipinlẹ Kogi nigba naa, ti wọn si sun un mọle pẹlu awọn dukia rẹ.

Ọjọ keje, oṣu kejila, ọdun naa ni wọn sin in.

Leave a Reply