Wọn ti dana sun banki mẹta ni Lẹkki

Ileefowopamọ mẹta la gbọ pe wọn ti dana sun ni Lekki ba a ṣe n sọ yii. Awọn banki mẹteẹta ọhun ni: Guaranty Trust Bank (GTB), Polaris Bank ati Access Bank to wa ni Admiralty Way.

ALAROYE gbọ pe ọpọ awọn ileetaja to wa ni agbegbe naa ni awọn janduku ti kọ lu. Wọn ti fọ ọpọ awọn ṣọọbu yii, ti wọn si n ko awọn nnkan oriṣiiriṣii to wa nibẹ lọ.

A gbọ pe eyi ko sẹyin bi awọn ṣọja ṣe lọọ doju ibọn kọ awọn ọdọ ti wọn kora jọ si Lẹkki ni itẹsiwaju iwọde SARS, lẹyin ti ijọba ṣofin konilegbele.

Leave a Reply