Adewale Adeoye
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ, Eko S.P Benjamin Hundeyin, ti sọ pe latari ki ileeṣẹ ọlọpaa le dẹkun iwa ibajẹ to wọpọ laarin awọn agbofinro kan lorileede yii lo mu ki wọn da Sageenti Ekpo Shimuyere, ti nọmba igbani-siṣẹ rẹ jẹ, 461645 duro lẹnu iṣẹ ijọba bayii. Ẹsun iwa ibajẹ, lilu araalu ni jibiti owo nla ati biba orukọ ileeṣẹ ọlọpaa ilẹ yii jẹ ni wọn fi kan an.
ALAROYE gbọ pe Sageenti Ekpo to n ṣiṣẹ ni teṣan ọlọpaa agbegbe Sogunlẹ, nijọba ibilẹ Ikeja, nipinlẹ Eko, ni wọn fẹsun gbigba ẹgbẹrun mejidinlọgọrun-un Naira lara owo to wa ninu akaunti ọgbẹni kan ti wọn forukọ bo laṣiiri lọna aitọ, eyi tileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko sọ pe ki i ṣohun to daa rara, ti ijiya nla si wa fẹni to ba ṣe bẹẹ.
Hundeyin ni, ‘Ọgbẹni kan ta a forukọ bo laṣiri lo waa fẹjọ Sajẹnti Ekpo sun awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko pe o gba foonu oun, to si gba ẹgbẹrun mejidinlọgọrun-un Naira jade ninu akaunti oun lakooko to da oun duro fun ayẹwo kan. ‘Loju-ẹṣẹ ta a ti gbọ nipa ẹsun naa la ti bẹrẹ si i ṣewadi lori ọrọ ọhun. Ohun ta a kọkọ ṣe ni pe, ṣe la ti Sajẹnti Ekpo mọ atimọle ọlọpaa, ko ma baa di iwadii wa lọwo. Lẹyin naa la pe oṣiṣẹ oni POS ti ọkunrin yii lo lati fi gba owo ọhun. Oni POS yii paapaa ti jẹwọ pe loootọ, oun loun ba Sajẹnti Ekpo gba owo naa jade. Lẹyin naa la tun yẹ akaunti Ekpo wo, ta a si ri owo naa nibẹ.
‘Eyi lo mu ki kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Eko paṣẹ pe ki wọn fiya to tọ jẹ agbofinro ọhun, ta a si ti gba aṣọ ijọba lọrun rẹ lori ohun to ṣe yii’.
Nipari ọrọ rẹ, Alujkoro ni igbesẹ tawọn gbe yii yoo le jẹ ẹkọ nla fun gbogbo awọn ọlọpaa yooku pe ki i ṣohun to daa kawọn to yẹ ki wọn maa daabo bo araalu tun maa rẹ wọn jẹ.