Wọn ti gba aṣọ ọlọpaa lọrun Inspẹkitọ Jonathan baale ile lo yinbọn pa l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko lawọn ti gba’ṣọ ọlọpaa lọrun oṣiṣẹ wọn kan, Inspẹkitọ Jonathan Kampani, wọn fọwọ osi juwe ile fun un latari ẹsun ti wọn fi kan an pe o yinbọn pa Ọgbẹni Jẹlili Bakare lọjọ kejidinlogun, oṣu kẹta yii.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, DSP Olumuyiwa Adejọbi, sọ f’ALAROYE pe lẹyin tawọn ṣe iwadii abẹle ni ilana iṣẹ ọlọpaa, gẹgẹ bawọn ṣe maa n ṣe tiru ẹsun bayii ba waye tan, awọn ẹri fihan pe Jonathan, ti nọmba iwọṣẹ rẹ jẹ AP No 278055 jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an, wọn ni ikọja-aaye ati iwa aibikita ni bo ṣe yinbọn pa ẹni ẹlẹni lọjọ buruku eṣu gbomi mu ọhun.

Wọn ni ibeere ti oloogbe naa beere lọwọ Jonathan pe ko sọ idi to fi fẹẹ maa tu apo oun wo foun ko to ohun to yẹ ko bi aribọn-yọ agbofinro yii ninu, debi to fi fibinu da ẹmi baale ile ẹni ọdun marundinlaaadọta naa legbodo, ninu ọgba ileetura Quinox Lounge, lagbegbe Ṣangotẹdo, tọkunrin naa ti n ṣiṣẹ.

Adejọbi ni pẹlu pe awọn ti sọ afurasi ọdaran yii dẹni ana lẹnu iṣẹ ọlọpaa, o ni ahaamọ ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ ni Panti, Yaba, lo ṣi wa, ibẹ naa lo si maa wa titi tawọn fi maa foju ẹ bale-ẹjọ laipẹ, tori ọran nla lo da, o si gbọdọ foju wina ofin.

Ṣaaju ni Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu, ti lọọ ṣabẹwo ibanikẹdun sawọn mọlẹbi Bakare niluu Ajiran, nijọba ibilẹ Eti-Ọsa, nipinlẹ Eko, o si ṣeleri fun wọn pe ileeṣẹ ọlọpaa maa ṣiṣẹ tọ idajọ ododo lẹyin lori ọrọ ibanujẹ to ṣẹlẹ ọhun.

Leave a Reply