Wọn ti gba awọn ọmọ ẹgbẹ OPC tọlọpaa mu nitori Wakili silẹ

Jide Alabi

Awọn ọlọpaa ti fi awọn ọmọ OPC mẹta ti wọn mu lori ọrọ Iskilu Wakili, Fulani to n da awọn ara Ibarapa laamu ti awọn ọmọ ẹgbẹ naa mu ni ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii.

Ni nnkan bii aago marun-un aabọ irọlẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ni wọn tu wọn silẹ lẹyin ti wọn gba beeli wọn.

Awọn ti wọn mu, ṣugbọn ti wọn ti gba itusilẹ ọhun ni Dauda Ramon, Awodele Adedigba ati Ramon Hassan.

Lati ọjọ Aiku ti awọn OPC ti mu ọkunrin naa ni awọn ọlọpaa ti gbe wọn ju satimọle, ẹsun ti wọn fi kan wọn ni pe wọn dana sun ile Wakilu, wọn si yinbọn pa eeyan kan.

Ọpọ eeyan lo bu ẹnu atẹ lu igbesẹ awọn agbofinro yii, paapaa nigba ti awọn OPC ṣalaye pe awọn eeyan Wakili ni wọn kọkọ yinbọn lu awọn, lasiko ija naa ni ibọn ba obinrin kan.

Leave a Reply