Wọn ti gbe igbimọ ti yoo gbọ awuyewuye ibo ipinlẹ Ondo kalẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Aarẹ ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun lorilẹ-ede yii, Onidaajọ Monica Dongban-Mensem, ti ṣe agbekalẹ ile-ẹjọ ti yoo gbọ awuyewuye to ba su yọ ninu eto idibo to fẹẹ waye lọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ ta a wa yii.

Akọwe ile-ẹjọ ti wọn ṣẹṣẹ gbe kalẹ ọhun, Ọgbẹni Musa Bako, fidi eyi mulẹ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ni koko ojuṣe ile-ẹjọ naa ni lati gbọ gbogbo awuyewuye yoowu to ba jẹ jade lasiko eto idibo gomina to fẹẹ waye naa.

O ni ijokoo awọn igbimọ ọhun yoo waye ninu ọgba ile-ẹjọ giga to wa niluu Akurẹ to jẹ olu-ilu ipinlẹ Ondo.

Leave a Reply