Wọn ti gbe oku awọn ologun to ku sinu ijamba ẹronpileeni de Abuja

Wọn ti gbe oku awọn ṣọja to padanu ẹmi wọn ninu ijamba ọkọ ofurufu lalẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, yii wa siluu Abuja.

Isin n lọ lọwọ nilana Musulumi fun awọn to jẹ Musulumi ninu wọn, nigba ti isin tawọn Onigbagbọ naa n lọ lọwọ lati bu eyẹ ikẹyin fun awọn akikanju to ku ọhun.

Itẹkuu awọn ologun to wa niluu Abuja ni wọn n ṣeto si lati sin wọn si.

Leave a Reply