Wọn ti gbe Sunday Igboho dele-ẹjọ

Faith Adebọla

Sunday Igboho ti wa nile-ẹjọ, igbẹjọ yoo si bẹrẹ ni ketẹ ti awọn agbẹjọro ati adajọ ti yoo gbọ ẹjọ naa ba ti wọle sibi igbẹjọ. Ọpọlọpọ awọn ọba, awọn ọmọ Yoruba to wa ni ilẹ Benin atawọn ti wọn lọ lati Naijiria ni wọn ti wa nile-ẹjọ bayii, ti wọn n reti ki igbẹjọ bẹrẹ ni pẹrẹu.

Ọpọ awọn eeyan ni ALAROYE gbọ pe wọn ko raaye wọle sinu ile-ẹjọ yii gẹgẹ bi ẹnikan to wa nibi igbẹjọ yii ṣe fi to wa leti.

O ni ọpọ eeyan lo wa nita ti wọn ko jẹ ki wọn wọle. Eyi ko si sẹyin iṣẹlẹ to ṣẹlẹ ni Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja, ti wọn kọkọ gbe Oloye Sunday Igboho lọ sile-ẹjọ, ti kootu naa si kun akunfaya debii pe o nira lati dari awọn ero naa.

Eyi ni wọn lo fa a ti wọn ko ṣe fun ọpọ eeyan ni anfaani lati wa ninu kootu yii, to jẹ pe  ita ni wọn duro si.

Awọn ọba Yoruba to wa ni Benin ko gbẹyin ninu awọn to wa ni kootu naa lati ṣatilẹyin fun Igboho.

Tẹ o ba gbagbe, lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ni Olubadan tilẹ Ibadan, Ọba Saliu Adetunji, naa ran awon ikọ kan lọ si orileede Olominira Benini lati ṣatilẹyin fun Igboho, ati lati wo bi ẹjọ naa yoo ṣe lo si.

Bi ijọba Naijria ko ba gbe ẹjọ mi-in dide yatọ si eyi ti ile-ẹjọ jokoo lori rẹ ni Ọjọbọ, Tọsidee ,to kọja, ireti wa pe wọn yoo da Sunday Igboho silẹ lonii, ọjọ Aje,  gẹgẹ bi ọkan ninu awọn agbẹjọro agba kan, Oluṣẹgun Fawọle ṣe sọ fun tẹlifiṣan ori ẹrọ ayelujara kan.

Leave a Reply