Wọn ti geeti ile-igbimọ mọ awọn aṣofin ẹgbẹ PDP l’Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ṣe lo da bii igba tawọn eeyan n wo fiimu agbelewo nile-igbimọ aṣofin ipinlẹ Ondo l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii,  pẹlu bawọn ẹsọ alaabo ṣe ti geeti mọ awọn aṣofin ẹgbẹ PDP meji lasiko ti wọn fẹẹ lọọ darapọ mọ awọn ẹgbẹ wọn nibi ijokoo ile.

Gbogbo akitiyan awọn aṣofin mejeeji, Ọnarebu Festus Akingbasọ to n soju awọn eeyan ijọba ibilẹ Idanre ati Rasheed Ẹlẹgbẹlẹyẹ to jẹ olori awọn ọmọ-ile to kere ju lọ lati rọna wọle lo ja si pabo lọjọ naa.

Aṣofin to n ṣoju awọn eeyan Iwọ-Oorun Ondo kin-in-ni, Ọnarebu Leonard Tọmide Akinribido, to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ ni gbogbo awọn aṣofin mẹsan-an ti awọn ko fọwọ si iwe iyọnipo Igbakeji Gomina, Ọnarebu Agboọla Ajayi, ni wọn n ti mọ ita, ti wọn ki i gba awọn laaye lati wọle nigbakuugba ti ijokoo ba n lọ lọwọ.

Igbakeji olori awọn ọmọ-ile to kere ju lọ ọhun ni ẹnu geeti ni wọn ti maa n da awọn pada, ti awọn ẹsọ alaabo yoo si maa sọ fawọn pe asẹ ti wọn pa fawọn lawọn n tẹle.

Ọjọ Aje, Mọnde, ọṣẹ yii, kan naa lawọn tọọgi kan di ẹnu ọna ile-igbimọ ọhun pa, ti wọn si kọ lati fun Igbakeji abẹnugan, Ọnarebu Irọju Ogundeji, ati aṣofin mi-in lanfaani lati wọle lọọ ṣe ojuṣe wọn lọjọ yii.

Leave a Reply