Wọn ti jawe oye le Ogunṣua Mọdakẹkẹ tuntun lori

Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Lẹyin oṣu kan ti Ogunṣua ilu Mọdakẹkẹ tẹlẹ, Ọba Moses Ọladẹjọ Oyediran, Ajombadi 111, waja, wọn ti jawe oye le ọba mi-in lori bayii.
Aarin ọja-ọba, ni Itamẹrin, niwaju aafin ọba ilu naa ni eto ọhun ti waye. Nibẹ ni wọn ti jawe oye le Oloye Joseph Olu Toriọla lori gẹgẹ bii ọba alade kẹta niluu naa.
Ẹni ọdun mejilelọgọrin ni Oloye Toriọla, oun si ni Ọtun Balogun ilu naa ki wọn too kede rẹ gẹgẹ bii Ogunṣua tuntun.
Ọmọ agboole Ogo, niluu Mọdakẹkẹ ni baba naa.

Leave a Reply