Wọn ti ji alaga kansu Iganna gbe o

Aderoounmu Kazeem

Ni bayii, igba miliọnu naira, lawọn ajinigbe ti wọn gbe alaga kansu Iganna, Ogbẹni Jacob Ọlayiwọla Adeleke, gbe lana-an ọjọ Aiku, Sannde.

ALAROYE gbọ pe ipade kan ni alaga kansu ọhun n lọ ki awọn ajinigbe too kọlu oun ati dẹrẹba ẹ, ti wọn si ji wọn gbe lọ.

Ilu kan ti wọn  pe ni Eluwa ni wọn ti kọlu wọn laarin Ado-Awaye si Okeho. Ẹni to ba wa sọrọ yii sọ pe lọwọ irọlẹ ni alaga kansu ọhun kuro niluu Iganna pẹlu dẹrẹba ẹ, ti wọn si kọri si Ibadan nibi ti wọn ti fẹẹ lọọ ṣe ipade pẹlu Gomina Ṣeyi Makinde, ki wọn too kọlu u, ti wọn si ji i gbe e salọ.

Ṣaaju akoko yii ni wọn sọ pe awọn eeyan Ado-Awaye, Iganna, Okeho atawọn ibomi-in to sunmọ ti n ri wahala ijinigbe.

Oni ọjọ Aje, Mọnde, yii gan an lawọn eeyan ti wọn ji alaga kansu ọhun gbe pe awọn eeyan ẹ, owo bii igba miliọnu naira gan-an ni wọn ni ki wọn lọọ mu wa, ti wọn ba ṣi fẹẹ foju kan an.

Eluwa ti wọn ti kọlu u yii ni wọn ti fẹẹ lọọ gbe mọto alaga ọhun bayii, bẹẹ lawọn fijilante atawọn ẹṣọ mi-in lagbegbe naa ti bẹ sinu igbo, ti wọn n wa awọn ọdaran naa kiri.

Leave a Reply