Wọn ji mẹrin gbe ninu awọn oṣiṣẹ ọkọ oju-irin Eko s’Ibadan, wọn tun pa ọlọpaa kan

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹ́òkúta

Mẹrin ninu awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ China to n mojuto ọkọ oju-irin igbalode tijọba n ṣe lati Eko lọ s’Ibadan ni wọn ti dawati bayii.

Awọn ajinigbe kan lo waa gbe wọn lọ tibọn-tibọn l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹfa, labule Adeaga-Alaagba, ti wọn ti n ṣiṣẹ lọwọ, nijọba ibilẹ Ọdẹda, nipinlẹ Ogun.

A gbọ pe awọn ajinigbe naa to mẹjọ, aṣọ dudu ni wọn wọ, gbariyẹ awọn Mọla ti wọn n pe ni Kaftan ni wọn faṣọ ọhun ran.

Bi wọn ṣe de, ọlọpaa to n ṣọ ibi tawọn oṣiṣẹ naa wa ni wọn kọkọ mu balẹ, wọn yinbọn fun un, wọn si ko mẹrin ninu awọn oṣiṣẹ naa sọkọ, wọn gbe wọn lọ raurau.

Awọn ọlọ́pàá atawọn oṣiṣẹ FRSC kan la gbọ pe wọn waa gbe oku ọlọpaa naa lọ.

Alukoro ọlọpaa Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, ti ko ba fidi eyi mulẹ ko ṣee ba sọrọ lasiko ti a n kọ iroyin yii lọwọ, nitori ko da atẹjiṣẹ ta a fi ranṣẹ si i pada.

Leave a Reply