Dada Ajikanje
Ba a ṣe n kọ iroyin yii, agọ ọlọpaa to wa ni Ikoyi ati Adeniji Adele, niluu Eko, ni wọn ko awọn ọdọ ti wọn mu pe wọn fẹẹ ṣewọde wọọrọwọ laaarọ ọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ yii, lọ.
Iroyin to tẹ ALAROYE lọwọ ni pe niṣe ni wọn da awọn eeyan naa si meji, ti wọn ko awọn kan lọ si agọ ọlọpaa Ikoyi, ti wọn si ko awọn kan lọ si Adeniji Adele. Ko ti i sẹni to le sọ boya wọn maa ti wọn mọle ni, tabi wọn maa gbe wọn lọ sile-ẹjọ.
Laaarọ yii ni wọn ko awọn eeyan naa nibi ti wọn para jọ si ni Too-Geeti Lẹkki, nibi ti wọn ti fẹẹ ṣewọde wọọrọwọ ta ko bi wọn ṣe ni wọn fẹẹ ṣi Too-Geeti naa pada lai ti i jẹ pe wọn yanju ọrọ naa tan. O ni bii igba ti wọn n jo jaginni yodo lori saare awọn to ku nibi iṣẹlẹ naa ni.