Wọn ti ko awọn ọmọlẹyin Igboho ti wọn ti mọle wa sile-ẹjọ l’Abuja

Faith Adebọla

Iroyin to tẹ wa lọwọ ni pe wọn ti gbe awọn mẹtala ti wọn ko nile Oloye Sunday Adeyẹmọ ti gbogbo eeyan mọ si Sunday Igboho, ni ọjọ kin-in-ni, oṣu keje, ọdun yii, lasiko ti awọn ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ DSS, ya bo ile naa to wa ni adugbo Soka, niluu Ibadan, wa si ile-ẹjọ giga kan niluu Abuja. Ireti wa pe wọn yoo fun awọn eeyan naa ni beeli lonii.

Tẹ o ba gbagbe, latigba ti awọn DSS ti ya bo ile Igboho, ti wọn paayan meji nibẹ, ti wọn si ko awọn mẹtala yii, ọkunrin mejila, obinrin kan, wa siluu Abuja ni wọn ti wa ni ahamọ. Gbogbo bi awọn agbẹjọro wọn si ṣe n wa sile-ẹjọ lati gba beeli wọn, awọn ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ ko yọnda awọn eeyan naa lati wa si kootu.

Ọṣẹ to kọja ti igbẹjọ naa tun waye ni adajọ paṣẹ pe wọn gbọdọ ko awọn eeyan naa wa si kootu.

Lọsẹ to kọja yii kan naa ni agbẹjọro awọn ọmọ ẹyin Igboho yii, Pẹlumi Ọlajẹngbesi, ba iweeroyin Punch sọrọ, to si fi aidunnu rẹ han si ipo ti awọn eeyan naa wa ati bi ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ ṣe n fi iya jẹ wọn pẹlu bi wọn ko ṣe ri ounjẹ to daa jẹ, ti eyi to jẹ obinrin ninu wọn ko si paarọ aṣọ lati ọjọ to ti debẹ.

ALAROYE yoo maa fi bi igbẹjọ naa ba ṣe lọ to yin leti.

Leave a Reply