Wọn ti ko mọkanla ninu awọn oluwọde tibọn ba lọ si ọsibitu kan ni Lekki

Iroyin to tẹ ALAROYE lọwọ bayii ni pe ileewosan aladaani kan ti wọn n pe ni Reddington Hospital, to wa ni Lekki, nipinlẹ Eko, ni wọn ko mọkanla ninu awọn ti ibọn awọn ṣọja ba lọ fun itọju.

Lọwọlọwọ yii, awọn eeyan naa wa nibẹ pẹlu awọn ọdọ ẹlẹgbẹ wọn ti wọn n sare kiri lati doola ẹmi wọn.

Aṣaalẹ ọjọ Isegun, Tusidee, ọsẹ yii, ni awọn ṣọja ṣina ibọn bo awọn oluwọde naa nibi ti wọn kora jọ si ni Lẹkki.

Iroyin ti a ko ti i le fidi rẹ mulẹ sọ pe meje ninu awọn ọdọ naa lo ti jade laye.

Leave a Reply