Wọn ti le ọlọpaa mẹta to fipa gbowo lọwọ akẹkọọ LASU lẹnu iṣẹ

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Awọn ọlọpaa mẹta nni,Inspẹkitọ Sunday John, Sajẹnti Jimọh Asimiya ati Sajẹnti Solomon Adedapọ ti wọn fipa gbowo lọwọ akẹkọọ LASU, Sheriff Adedigba, l’Owode-Ẹgba, ti padanu iṣẹ wọn bayii, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti gbaṣẹ lọwọ wọn.

Ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ni aṣiri awọn ọlọpaa naa tu, lẹyin ti wọn fipa gba ẹgbẹrun lọna aadọjọ ati mẹta naira, (153,000) lọwọ akẹkọọ to n lọ s’Ekoo lati Abẹokuta.

Ori ẹka ayelujara ni Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Edward Ajogun, ti gbọ nipa ohun ti awọn ọlọpaa naa ṣe, ẹsẹkẹsẹ lo si ti pe DPO teṣan Owode-Ẹgba lati wa awọn ọlọpaa naa jade. Wọn kọkọ fi wọn si yara ahamọ, wọn si ni wọn yoo gba idajọ wọn laipẹ.

Nigba ti yoo fi di ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹrin yii, idajọ wọn de. DSP Abimbọla Oyeyẹmi sọ ọ di mimọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti le awọn mẹta yii danu lẹnu iṣẹ ọlọpaa, ki ohun ti wọn ṣe le jẹ ẹkọ fawọn abanilojujẹ agbofinro mi-in to ba n ṣe bẹẹ tabi ti wọn ba tun fẹẹ dan iru ẹ wo lọjọ iwaju.

Wọn ti da owo Sheriiff pada fun un ni tiẹ, nitori bọwọ ṣe tẹ awọn ọlọpaa mẹta naa ni wọn ti gbowo ọhun pada lọwọ wọn.

Bi ẹ ba kofiri ọlọpaa to n fipa gbowo lọwọ ẹnikẹni, ẹ ma jẹ ko pẹ ti ẹ oo fi fẹjọ rẹ sun ni olu ileeṣẹ ọlọpaa, bẹẹ ni CP Edward Ajogun wi.

Leave a Reply