Wọn ti mu Aafaa Jamiu to fẹẹ fọmọ ọdun mẹẹẹdogun  ṣoogun owo ni Sango

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Aafaa Amọdu Jamiu ree, ẹni ọdun mẹtadinlogoji ni. Awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti mu un bayii, wọn lo ji ọmọbinrin ọmọ ọdun mẹẹẹdogun kan gbe pẹlu erongba ati fi i ṣe etutu ọrọ, oogun owo, ni Sango.

Ọjọ karun-un, oṣu kẹrin yii, lọwọ ba Aafaa Jamiu, iyẹn lẹyin ti ọmọbinrin to ji gbe naa lọọ fẹjọ sun ni teṣan ọlọpaa Sango. DSP Abimbọla Oyeyẹmi ṣalaye pe ọmọ naa sọ fawọn ọlọpaa pe jẹẹjẹ oun loun n ti ibi iṣẹ bọ lọjọ naa, boun ṣe pade aafaa yii niyẹn ni nnkan bii aago marun-un aabọ irọlẹ.

Ọmọbinrin yii ṣalaye pe Aafaa Jamiu da oun duro, o si fi kinni kan gba oun, bẹẹ lo paṣẹ pe koun ka lọ, oun si tẹle e wọ ile akọku kan to mu oun wọ.

Ninu ile naa lo ni Aafaa Jamiu ti ja oun sihooho, o si fi ankaṣiifu funfun kan nu oju ara oun, bẹẹ lo fi nu gbogbo ara oun kari pẹlu.

Aṣe ẹnikan n ri wọn latọọkan, gbogbo ohun ti aafaa n ṣe fọmọ naa ni tọhun n wo. Nigba to si di pe ọmọbinrin naa ko mọ ibi to wa mọ, to kan wa nibẹ bẹẹ ni ẹni naa yọju si wọn, bawọn ọlọpaa ṣe wi, n lo ba pariwo le Aafaa Jamiu lori.

Nigba tọwọ ọlọpaa ba aafaa, o jẹwọ pe loootọ loun ṣe ohun ti wọn fẹsun ẹ kan oun yii.

Aafaa Amọdu sọ pe oun fẹẹ fi aisan buruku kan ṣe ọmọbinrin naa ni, to bẹẹ ti yoo maa ṣe aarẹ, ti awọn obi rẹ yoo fi gbe e wa sọdọ oun, toun yoo si maa gba owo buruku lọwọ wọn fun itọju rẹ.

Aafaa sọ pe oun ti ṣe bẹẹ fawọn meji kan ri to jẹ owo nla loun fi gba lọwọ awọn eeyan wọn.

Awọn ọlọpaa lọ sile aafaa yii lati yẹ ẹ wo, oriṣiiriṣii apẹ ijoogun ni wọn ba nibẹ, wọn si ya fọto rẹ ki gbogbo aye le ri ohun ti Aafaa Jamiu Amọdu fi n ṣagbara.

Ni bayii ṣa, wọn ti taari aafaa si ẹka iwadii, wọn fẹ ko ṣalaye siwaju si i nipa awọn itu to ti pa ri ki wọn too mu un.

Leave a Reply